Përkthimi i kuptimeve të Kuranit Fisnik - Përkthimi në gjuhën joruba - Ebu Rahime Majkëll

external-link copy
185 : 7

أَوَلَمۡ يَنظُرُواْ فِي مَلَكُوتِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ وَأَنۡ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ قَدِ ٱقۡتَرَبَ أَجَلُهُمۡۖ فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ

Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?[1] info

1. Gbólóhùn yìí "Nígbà náà, “hadīth wo” ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?" àti irú rẹ̀ tó wà nínú sūrah al-Mursalāt; 77:50 àti sūrah al-Jāthiyah; 45:6, kò túmọ̀ sí pé kò sí hadīth Ànábì torí pé, hadīth Ànábì náà ni sunnah Ànábì.

التفاسير: