Përkthimi i kuptimeve të Kuranit Fisnik - Përkthimi në gjuhën joruba - Ebu Rahime Majkëll

Numri i faqes:close

external-link copy
109 : 3

وَلِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ

Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí. info
التفاسير:

external-link copy
110 : 3

كُنتُمۡ خَيۡرَ أُمَّةٍ أُخۡرِجَتۡ لِلنَّاسِ تَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَتَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَتُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِۗ وَلَوۡ ءَامَنَ أَهۡلُ ٱلۡكِتَٰبِ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۚ مِّنۡهُمُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَأَكۡثَرُهُمُ ٱلۡفَٰسِقُونَ

Ẹ jẹ́ ìjọ tó lóore jùlọ, tí A gbé dìde fún àwọn ènìyàn; ẹ̀ ń pàṣẹ ohun rere, ẹ̀ ń kọ ohun burúkú, ẹ sì gbàgbọ́ nínú Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn ahlul-kitāb gbàgbọ́ lódodo ni, ìbá lóore jùlọ fún wọn. Onígbàgbọ́ òdodo wà nínú wọn,[1] ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn sì ni òbìlẹ̀jẹ́. info

1. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí ìpèpè Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - dé bá, tí wọ́n sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, wọ́n sì gba ’Islām.

التفاسير:

external-link copy
111 : 3

لَن يَضُرُّوكُمۡ إِلَّآ أَذٗىۖ وَإِن يُقَٰتِلُوكُمۡ يُوَلُّوكُمُ ٱلۡأَدۡبَارَ ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ

Wọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fún yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́. info
التفاسير:

external-link copy
112 : 3

ضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلذِّلَّةُ أَيۡنَ مَا ثُقِفُوٓاْ إِلَّا بِحَبۡلٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَحَبۡلٖ مِّنَ ٱلنَّاسِ وَبَآءُو بِغَضَبٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلۡمَسۡكَنَةُۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانُواْ يَكۡفُرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَيَقۡتُلُونَ ٱلۡأَنۢبِيَآءَ بِغَيۡرِ حَقّٖۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَواْ وَّكَانُواْ يَعۡتَدُونَ

Àbùkù yóò máa bá wọn níbikíbi tí ọwọ́ àwọn (mùsùlùmí) bá ti bà wọ́n àfi (tí wọ́n bá ń bẹ) pẹ̀lú àdéhùn àti ààbò láti ọ̀dọ̀ Allāhu (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gba ’Islām) àti àdéhùn àti ààbò láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn (ìyẹn ni pé, kí wọ́n gbà láti máa san owó ìsákọ́lẹ̀ fún ìjọba ’Islām). Wọ́n ṣẹ́rí padà pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì kó òṣì bá wọn. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n tún ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu ààlà. info
التفاسير:

external-link copy
113 : 3

۞ لَيۡسُواْ سَوَآءٗۗ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ أُمَّةٞ قَآئِمَةٞ يَتۡلُونَ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ ءَانَآءَ ٱلَّيۡلِ وَهُمۡ يَسۡجُدُونَ

(Àwọn onítírà) kò rí bákan náà. Ìjọ kan tó dúró déédé wà nínú àwọn onítírà, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Allāhu ní àkókò òru, tí wọ́n sì ń forí kanlẹ̀ (lórí ìrun). info
التفاسير:

external-link copy
114 : 3

يُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَيَأۡمُرُونَ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَيَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَيُسَٰرِعُونَ فِي ٱلۡخَيۡرَٰتِۖ وَأُوْلَٰٓئِكَ مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ

Wọ́n gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Wọ́n ń pàṣẹ ohun rere, wọ́n ń kọ ohun burúkú, wọ́n sì ń yara níbi àwọn iṣẹ́ olóoore. Àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn ẹni rere.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah 110 tó ṣíwájú.

التفاسير:

external-link copy
115 : 3

وَمَا يَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَلَن يُكۡفَرُوهُۗ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلۡمُتَّقِينَ

Ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe ní iṣẹ́ rere, A ò níí jẹ́ kí ẹ̀san rẹ̀ gbé. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀). info
التفاسير: