Ibisobanuro bya qoran ntagatifu - Ibisobanuro bya Qur'an Ntagatifu mu rurimi rw'ikiyoruba - Abu Rahima Mikhail

numero y'urupapuro:close

external-link copy
47 : 41

۞ إِلَيۡهِ يُرَدُّ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِۚ وَمَا تَخۡرُجُ مِن ثَمَرَٰتٖ مِّنۡ أَكۡمَامِهَا وَمَا تَحۡمِلُ مِنۡ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلۡمِهِۦۚ وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ أَيۡنَ شُرَكَآءِي قَالُوٓاْ ءَاذَنَّٰكَ مَا مِنَّا مِن شَهِيدٖ

Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò máa dá ìmọ̀ Àkókò náà padà sí. Kò sí èso kan tí ó máa jáde nínú apó rẹ̀, obìnrin kan kò sì níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Ó sì máa pè wọ́n pé: “Ibo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi (tí ẹ jọ́sìn fún) wà?”[1] Wọ́n á wí pé: “Àwa ń jẹ́ kí O mọ̀ pé kò sí olùjẹ́rìí kan nínú wa (tí ó máa jẹ́rìí pé, O ní akẹgbẹ́.)” info

1. Allāhu kò ní akẹgbẹ́ ẹyọ kan áḿbọ̀sìbọ́sí àwọn akẹgbẹ́. Àmọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ló sọ àwọn òrìṣà wọn di akẹgbẹ́ Allāhu. Ìpè àbùkù àti ìpè ẹ̀sín ni èyí máa jẹ́ fún àwọn abọ̀rìṣà àti àwọn òrìṣà wọn ní ọjọ́ ìpè náà, ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde.

التفاسير:

external-link copy
48 : 41

وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَدۡعُونَ مِن قَبۡلُۖ وَظَنُّواْ مَا لَهُم مِّن مَّحِيصٖ

Ohun tí wọ́n ń pè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.[1] Wọ́n sì mọ̀ ní àmọ̀dájú pé, kò sí ibùsásí kan fún àwọn. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:24.

التفاسير:

external-link copy
49 : 41

لَّا يَسۡـَٔمُ ٱلۡإِنسَٰنُ مِن دُعَآءِ ٱلۡخَيۡرِ وَإِن مَّسَّهُ ٱلشَّرُّ فَيَـُٔوسٞ قَنُوطٞ

Ènìyàn kò kó ṣúṣú níbi àdúà (láti tọrọ) oore. Tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, ó máa di olùsọ̀rètínù, olùjákànmùná. info
التفاسير:

external-link copy
50 : 41

وَلَئِنۡ أَذَقۡنَٰهُ رَحۡمَةٗ مِّنَّا مِنۢ بَعۡدِ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُ لَيَقُولَنَّ هَٰذَا لِي وَمَآ أَظُنُّ ٱلسَّاعَةَ قَآئِمَةٗ وَلَئِن رُّجِعۡتُ إِلَىٰ رَبِّيٓ إِنَّ لِي عِندَهُۥ لَلۡحُسۡنَىٰۚ فَلَنُنَبِّئَنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِمَا عَمِلُواْ وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنۡ عَذَابٍ غَلِيظٖ

Dájúdájú tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún un láti ọ̀dọ̀ Wa lẹ́yìn aburú tí ó fọwọ́ bà á, dájúdájú ó máa wí pé: “Èyí ni tèmi. Èmi kò sì ní àmọ̀dájú pé Àkókò náà máa ṣẹlẹ̀. Àti pé dájúdájú tí Wọ́n bá dá mi padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa mi, dájúdájú rere tún wà fún mi ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀.” Dájúdájú Àwa yóò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú A sì máa fún wọn ní ìyà tó nípọn tọ́ wò. info
التفاسير:

external-link copy
51 : 41

وَإِذَآ أَنۡعَمۡنَا عَلَى ٱلۡإِنسَٰنِ أَعۡرَضَ وَنَـَٔا بِجَانِبِهِۦ وَإِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ فَذُو دُعَآءٍ عَرِيضٖ

Àti pé nígbà tí A bá ṣe ìdẹ̀ra fún ènìyàn, ó máa gbúnrí (kúrò ní ọ̀dọ̀ Wa). Ó sì máa ṣègbéraga. Nígbà tí aburú bá sì fọwọ́ bà á, nígbà náà l’ó máa di aládùáà rẹgẹdẹ. info
التفاسير:

external-link copy
52 : 41

قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كَانَ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ ثُمَّ كَفَرۡتُم بِهِۦ مَنۡ أَضَلُّ مِمَّنۡ هُوَ فِي شِقَاقِۭ بَعِيدٖ

Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé al-Ƙur’ān wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu, lẹ́yìn náà tí ẹ ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ (ṣé ẹ̀yin kò ti wà nínú ìyapa bí?)” Ta l’ó ṣìnà ju ẹni tí ó wà nínú ìyapa tó jìnnà (sí òdodo)! info
التفاسير:

external-link copy
53 : 41

سَنُرِيهِمۡ ءَايَٰتِنَا فِي ٱلۡأٓفَاقِ وَفِيٓ أَنفُسِهِمۡ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَهُمۡ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّۗ أَوَلَمۡ يَكۡفِ بِرَبِّكَ أَنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ

A óò máa fi àwọn àmì Wa hàn wọ́n nínú òfurufú àti nínú ẹ̀mí ara wọn títí ó máa fi hàn kedere sí wọn pé dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo. Ǹjẹ́ Olúwa rẹ kò tó kí ó jẹ́ pé dájúdájú Òun ni Arínú-róde lórí gbogbo n̄ǹkan? info
التفاسير:

external-link copy
54 : 41

أَلَآ إِنَّهُمۡ فِي مِرۡيَةٖ مِّن لِّقَآءِ رَبِّهِمۡۗ أَلَآ إِنَّهُۥ بِكُلِّ شَيۡءٖ مُّحِيطُۢ

Gbọ́, dájúdájú wọ́n wà nínú iyèméjì nípa ìpàdé Olúwa wọn. Gbọ́, dájúdájú Allāhu yí gbogbo n̄ǹkan ká. info
التفاسير: