Ibisobanuro bya qoran ntagatifu - Ibisobanuro bya Qur'an Ntagatifu mu rurimi rw'ikiyoruba - Abu Rahima Mikhail

external-link copy
47 : 41

۞ إِلَيۡهِ يُرَدُّ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِۚ وَمَا تَخۡرُجُ مِن ثَمَرَٰتٖ مِّنۡ أَكۡمَامِهَا وَمَا تَحۡمِلُ مِنۡ أُنثَىٰ وَلَا تَضَعُ إِلَّا بِعِلۡمِهِۦۚ وَيَوۡمَ يُنَادِيهِمۡ أَيۡنَ شُرَكَآءِي قَالُوٓاْ ءَاذَنَّٰكَ مَا مِنَّا مِن شَهِيدٖ

Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò máa dá ìmọ̀ Àkókò náà padà sí. Kò sí èso kan tí ó máa jáde nínú apó rẹ̀, obìnrin kan kò sì níí lóyún, kò sì níí bímọ àfi pẹ̀lú ìmọ̀ Rẹ̀. (Rántí) ọjọ́ tí Ó sì máa pè wọ́n pé: “Ibo ni àwọn akẹgbẹ́ Mi (tí ẹ jọ́sìn fún) wà?”[1] Wọ́n á wí pé: “Àwa ń jẹ́ kí O mọ̀ pé kò sí olùjẹ́rìí kan nínú wa (tí ó máa jẹ́rìí pé, O ní akẹgbẹ́.)” info

1. Allāhu kò ní akẹgbẹ́ ẹyọ kan áḿbọ̀sìbọ́sí àwọn akẹgbẹ́. Àmọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ló sọ àwọn òrìṣà wọn di akẹgbẹ́ Allāhu. Ìpè àbùkù àti ìpè ẹ̀sín ni èyí máa jẹ́ fún àwọn abọ̀rìṣà àti àwọn òrìṣà wọn ní ọjọ́ ìpè náà, ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde.

التفاسير: