Ibisobanuro bya qoran ntagatifu - Ibisobanuro bya Qur'an Ntagatifu mu rurimi rw'ikiyoruba - Abu Rahima Mikhail

numero y'urupapuro:close

external-link copy
62 : 38

وَقَالُواْ مَا لَنَا لَا نَرَىٰ رِجَالٗا كُنَّا نَعُدُّهُم مِّنَ ٱلۡأَشۡرَارِ

Wọ́n tún wí pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀ sí wa tí a kò rí àwọn ọkùnrin kan, àwọn tí à ń kà mọ́ àwọn ẹni burúkú. info
التفاسير:

external-link copy
63 : 38

أَتَّخَذۡنَٰهُمۡ سِخۡرِيًّا أَمۡ زَاغَتۡ عَنۡهُمُ ٱلۡأَبۡصَٰرُ

Ṣèbí a fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí àwọn ojú ti fò wọ́n ni (l’a ò fi rí wọn nínú Iná)?” info
التفاسير:

external-link copy
64 : 38

إِنَّ ذَٰلِكَ لَحَقّٞ تَخَاصُمُ أَهۡلِ ٱلنَّارِ

Dájúdájú ìyẹn, àríyànjiyàn àwọn èrò inú Iná, òdodo mà ni. info
التفاسير:

external-link copy
65 : 38

قُلۡ إِنَّمَآ أَنَا۠ مُنذِرٞۖ وَمَا مِنۡ إِلَٰهٍ إِلَّا ٱللَّهُ ٱلۡوَٰحِدُ ٱلۡقَهَّارُ

Sọ pé: “Èmi ni olùkìlọ̀. Àti pé kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo, Olùborí. info
التفاسير:

external-link copy
66 : 38

رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡغَفَّٰرُ

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì, Alágbára, Aláforíjìn.” info
التفاسير:

external-link copy
67 : 38

قُلۡ هُوَ نَبَؤٌاْ عَظِيمٌ

Sọ pé: “(al-Ƙur’ān) ni ìró ńlá. info
التفاسير:

external-link copy
68 : 38

أَنتُمۡ عَنۡهُ مُعۡرِضُونَ

Ẹ̀yin sì ń gbúnrí kúrò níbẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
69 : 38

مَا كَانَ لِيَ مِنۡ عِلۡمِۭ بِٱلۡمَلَإِ ٱلۡأَعۡلَىٰٓ إِذۡ يَخۡتَصِمُونَ

Èmi kò sì nímọ̀ nípa àwọn mọlāika tí ó wà ní àyè gíga nígbà tí wọ́n ń ṣàròyé. info
التفاسير:

external-link copy
70 : 38

إِن يُوحَىٰٓ إِلَيَّ إِلَّآ أَنَّمَآ أَنَا۠ نَذِيرٞ مُّبِينٌ

Kí ni wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi bí kò ṣe pé èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.” info
التفاسير:

external-link copy
71 : 38

إِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِنِّي خَٰلِقُۢ بَشَرٗا مِّن طِينٖ

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò dá abara kan láti inú ẹrẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
72 : 38

فَإِذَا سَوَّيۡتُهُۥ وَنَفَخۡتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُواْ لَهُۥ سَٰجِدِينَ

Nígbà tí Mo bá ṣe é tó dọ́gba jálẹ̀ tán, tí Mo sì fẹ́ nínú atẹ́gùn ẹ̀mí tí Mo dá sínú rẹ̀, nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un, kí ẹ forí kanlẹ̀ kí i.” info
التفاسير:

external-link copy
73 : 38

فَسَجَدَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ كُلُّهُمۡ أَجۡمَعُونَ

Gbogbo àwọn mọlāika pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i. info
التفاسير:

external-link copy
74 : 38

إِلَّآ إِبۡلِيسَ ٱسۡتَكۡبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ

Àyàfi ’Iblīs, tí ó ṣègbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́. info
التفاسير:

external-link copy
75 : 38

قَالَ يَٰٓإِبۡلِيسُ مَا مَنَعَكَ أَن تَسۡجُدَ لِمَا خَلَقۡتُ بِيَدَيَّۖ أَسۡتَكۡبَرۡتَ أَمۡ كُنتَ مِنَ ٱلۡعَالِينَ

(Allāhu) sọ pé: “’Iblīs, kí l’ó kọ̀ fún ọ láti forí kanlẹ̀ kí ohun tí Mo fi ọwọ́ Mi méjèèjì dá? Ṣé o ṣègbéraga ni tàbí o wà nínú àwọn ẹni gíga?” info
التفاسير:

external-link copy
76 : 38

قَالَ أَنَا۠ خَيۡرٞ مِّنۡهُ خَلَقۡتَنِي مِن نَّارٖ وَخَلَقۡتَهُۥ مِن طِينٖ

Ó wí pé: “Èmi lóore jù ú lọ; O dá èmi láti ara iná. O sì dá òun láti ara ẹrẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
77 : 38

قَالَ فَٱخۡرُجۡ مِنۡهَا فَإِنَّكَ رَجِيمٞ

(Allāhu) sọ pé: “Jáde kúrò nínú (Ọgbà Ìdẹ̀ra) nítorí pé, dájúdájú ìwọ ni ẹni ẹ̀kọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
78 : 38

وَإِنَّ عَلَيۡكَ لَعۡنَتِيٓ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلدِّينِ

Àti pé dájúdájú ègún Mi yóò wà lórí rẹ títí di Ọjọ́ ẹ̀san.” info
التفاسير:

external-link copy
79 : 38

قَالَ رَبِّ فَأَنظِرۡنِيٓ إِلَىٰ يَوۡمِ يُبۡعَثُونَ

(aṣ-Ṣaetọ̄n) wí pé: “Olúwa mi, lọ́ mi lára títí di ọjọ́ tí Wọn yóò gbé ẹ̀dá dìde.” info
التفاسير:

external-link copy
80 : 38

قَالَ فَإِنَّكَ مِنَ ٱلۡمُنظَرِينَ

(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ìwọ wà nínú àwọn tí wọ́n máa lọ́ lára info
التفاسير:

external-link copy
81 : 38

إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡوَقۡتِ ٱلۡمَعۡلُومِ

títí di ọjọ́ àkókò tí A ti mọ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
82 : 38

قَالَ فَبِعِزَّتِكَ لَأُغۡوِيَنَّهُمۡ أَجۡمَعِينَ

(aṣ-Ṣaetọ̄n) wí pé: “Mo fi agbára Rẹ búra, dájúdájú èmi yóò kó gbogbo wọn sínú ìṣìnà info
التفاسير:

external-link copy
83 : 38

إِلَّا عِبَادَكَ مِنۡهُمُ ٱلۡمُخۡلَصِينَ

àfi àwọn ẹrúsìn Rẹ, àwọn tí O ṣà lẹ́ṣà (fún ìgbàgbọ́ òdodo) nínú wọn.” info
التفاسير: