Ibisobanuro bya qoran ntagatifu - Ibisobanuro bya Qur'an Ntagatifu mu rurimi rw'ikiyoruba - Abu Rahima Mikhail

numero y'urupapuro:close

external-link copy
43 : 38

وَوَهَبۡنَا لَهُۥٓ أَهۡلَهُۥ وَمِثۡلَهُم مَّعَهُمۡ رَحۡمَةٗ مِّنَّا وَذِكۡرَىٰ لِأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ

A sì ta á lọ́rẹ àwọn ará ilé rẹ̀ (padà) àti irú wọn pẹ̀lú wọn. (Ó jẹ́) ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa àti ìrántí fún àwọn onílàákàyè. info
التفاسير:

external-link copy
44 : 38

وَخُذۡ بِيَدِكَ ضِغۡثٗا فَٱضۡرِب بِّهِۦ وَلَا تَحۡنَثۡۗ إِنَّا وَجَدۡنَٰهُ صَابِرٗاۚ نِّعۡمَ ٱلۡعَبۡدُ إِنَّهُۥٓ أَوَّابٞ

Fi ọwọ́ rẹ mú ìdì igi koríko tútù kí o fi lu (ìyàwó) rẹ. Má ṣe yapa ìbúra rẹ.[1] Dájúdájú Àwa rí (’Ayyūb) ní onísùúrù. Ẹrúsìn rere ni. Dájúdájú olùṣẹ́rí sí ọ̀dọ̀ Allāhu ni (nípa ìronúpìwàdà). info

1. Ní àsìkò tí àìlera wà fún Ànábì ’Ayyūb - kí ọlà Allāhu máa bá a -, ìyàwó rẹ̀ ṣẹ̀ ẹ́ ní ẹ̀ṣẹ̀ kan. Ànábì ’Ayyūb sì fi Allāhu búra pé òun yóò lù ú ní ẹgba ọgọ́rùn-ún lórí àṣìṣe náà tí òun bá gbádùn.

التفاسير:

external-link copy
45 : 38

وَٱذۡكُرۡ عِبَٰدَنَآ إِبۡرَٰهِيمَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ أُوْلِي ٱلۡأَيۡدِي وَٱلۡأَبۡصَٰرِ

Ṣèrántí àwọn ẹrúsìn Wa, (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb; àwọn alágbára àti olùríran (nípa ẹ̀sìn). info
التفاسير:

external-link copy
46 : 38

إِنَّآ أَخۡلَصۡنَٰهُم بِخَالِصَةٖ ذِكۡرَى ٱلدَّارِ

Dájúdájú Àwa ṣà wọ́n lẹ́ṣà pẹ̀lú ẹ̀ṣà kan, (òhun ni) ìrántí Ilé náà (ilé Ìkẹ́yìn). info
التفاسير:

external-link copy
47 : 38

وَإِنَّهُمۡ عِندَنَا لَمِنَ ٱلۡمُصۡطَفَيۡنَ ٱلۡأَخۡيَارِ

Dájúdájú wọ́n wà nínú àwọn ẹni ẹ̀ṣà, ẹni rere jùlọ ní ọ̀dọ̀ Wa. info
التفاسير:

external-link copy
48 : 38

وَٱذۡكُرۡ إِسۡمَٰعِيلَ وَٱلۡيَسَعَ وَذَا ٱلۡكِفۡلِۖ وَكُلّٞ مِّنَ ٱلۡأَخۡيَارِ

Ṣèrántí (àwọn Ànábì) ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘ àti Thul-Kifl. Ìkọ̀ọ̀kan wọn wà nínú àwọn ẹni rere jùlọ. info
التفاسير:

external-link copy
49 : 38

هَٰذَا ذِكۡرٞۚ وَإِنَّ لِلۡمُتَّقِينَ لَحُسۡنَ مَـَٔابٖ

Èyí ni ìrántí. Àti pé dájúdájú àbọ̀ rere wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu). info
التفاسير:

external-link copy
50 : 38

جَنَّٰتِ عَدۡنٖ مُّفَتَّحَةٗ لَّهُمُ ٱلۡأَبۡوَٰبُ

Àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére (ni). Wọ́n sì máa ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ sílẹ̀ fún wọn. info
التفاسير:

external-link copy
51 : 38

مُتَّكِـِٔينَ فِيهَا يَدۡعُونَ فِيهَا بِفَٰكِهَةٖ كَثِيرَةٖ وَشَرَابٖ

Wọn yóò rọ̀gbọ̀kú nínú rẹ̀. Wọn yóò máa bèèrè fún àwọn èso púpọ̀ àti ohun mímu nínú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
52 : 38

۞ وَعِندَهُمۡ قَٰصِرَٰتُ ٱلطَّرۡفِ أَتۡرَابٌ

Àwọn obìnrin tí kì í wo ẹlòmíìràn, tí ọjọ́ orí wọn kò jura wọn lọ yó sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn. info
التفاسير:

external-link copy
53 : 38

هَٰذَا مَا تُوعَدُونَ لِيَوۡمِ ٱلۡحِسَابِ

Èyí ni ohun tí Wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún yín fún Ọjọ́ ìṣírò-iṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
54 : 38

إِنَّ هَٰذَا لَرِزۡقُنَا مَا لَهُۥ مِن نَّفَادٍ

Dájúdájú èyí ni arísìkí Wa. Kò sì níí tán. info
التفاسير:

external-link copy
55 : 38

هَٰذَاۚ وَإِنَّ لِلطَّٰغِينَ لَشَرَّ مَـَٔابٖ

Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Àti pé dájúdájú àbọ̀ burúkú ni ti àwọn alágbèéré (sí Allāhu). info
التفاسير:

external-link copy
56 : 38

جَهَنَّمَ يَصۡلَوۡنَهَا فَبِئۡسَ ٱلۡمِهَادُ

Iná Jahanamọ ni wọn yó wọ̀. Ó sì burú ní ibùgbé. info
التفاسير:

external-link copy
57 : 38

هَٰذَا فَلۡيَذُوقُوهُ حَمِيمٞ وَغَسَّاقٞ

Èyí (rí bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, kí wọ́n tọ́ ọ wò; omi tó gbóná parí àti àwọnúwẹ̀jẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
58 : 38

وَءَاخَرُ مِن شَكۡلِهِۦٓ أَزۡوَٰجٌ

Oríṣiríṣi (ìyà) mìíràn bí irú rẹ̀ (tún wà fún wọn). info
التفاسير:

external-link copy
59 : 38

هَٰذَا فَوۡجٞ مُّقۡتَحِمٞ مَّعَكُمۡ لَا مَرۡحَبَۢا بِهِمۡۚ إِنَّهُمۡ صَالُواْ ٱلنَّارِ

Èyí ni ìjọ kan tó máa wọ inú Iná pẹ̀lú yín. (Àwọn aṣíwájú nínú Iná sì máa wí pé:) “Kò sí máawolẹ̀-máarọra fún wọn.” Dájúdájú wọn yóò wọ inú Iná ni. info
التفاسير:

external-link copy
60 : 38

قَالُواْ بَلۡ أَنتُمۡ لَا مَرۡحَبَۢا بِكُمۡۖ أَنتُمۡ قَدَّمۡتُمُوهُ لَنَاۖ فَبِئۡسَ ٱلۡقَرَارُ

(Àwọn ọmọlẹ́yìn nínú Iná) máa wí pé: “Rárá, ẹ̀yin náà kò sí máawolẹ̀-máarọra fún yín. Ẹ̀yin l’ẹ pè wá síbi èyí (tó bí Iná).” Ó sì burú ní ibùgbé. info
التفاسير:

external-link copy
61 : 38

قَالُواْ رَبَّنَا مَن قَدَّمَ لَنَا هَٰذَا فَزِدۡهُ عَذَابٗا ضِعۡفٗا فِي ٱلنَّارِ

Wọ́n (tún) wí pé: “Olúwa wa, ẹni tí ó pè wá (síbi ìyà) yìí, ṣe àlékún àdìpèlé ìyà fún un nínú Iná.” info
التفاسير: