1. Ìyẹn ni pé, wọ́n ti sọ fún Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - tẹ́lẹ̀ pé, ibi tí wọ́n bá gbàgbé ẹja sí, ibẹ̀ ni wọ́n máa ti pàdé ẹni tí ó ń lọ ṣàbẹ̀wò rẹ̀.
1. Ẹ̀kọ́ pàtàkì tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fẹ́ kọ́ Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - nípa ìrìn-àjò rẹ̀ sọ́dọ̀ Kidr ni pé, ìmọ̀ nípa òfin àti ìlànà ’Islām, èyí tí Allāhu fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra wọn díẹ̀díẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Ànábì kan sí òmíràn. Àti pé kò rọrùn fún ẹnì kan nínú wọn láti jẹ́ alámọ̀tán ohun gbogbo. Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - nìkan ṣoṣo sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.