1. Āyah yìí kò sọ kíkọ́ mọ́sálásí sórí sàréè di ẹ̀tọ́ bí kò ṣe pé, ó ń sọ nípa ohun tí àwọn oníjàgídíjàgan kan ṣe lásìkò náà.
1. Okùnfà āyah yìí ni pé, nígbà tí àwọn yẹhudi wá bi Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - léèrè nípa ọ̀rọ̀ àwọn ará inú ọ̀gbun àpáta pẹ̀lú èròǹgbà wọn pé tí ó bá jẹ́ Ànábì Ọlọ́hun ní ti òdodo, ó yẹ kí ó nímọ̀ nípa wọn, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ fún wọn pé kí wọ́n wá gbọ́ ìtàn wọn ní ọjọ́ kejì pẹ̀lú èròǹgbà rẹ̀ pé Allāhu á ti fi ìmísí nípa wọn ránṣẹ́ sí òun. Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò sì sọ fún àwọn yẹhudi náà pé “tí Allāhu bá fẹ́.” Àmọ́ àì sọ bẹ́ẹ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ọjọ́ àdéhùn tó ṣe fún wọn yẹ̀.