Vertaling van de betekenissen Edele Qur'an - Yoruba vertaling - Aboe Rahimah Mikail

Pagina nummer:close

external-link copy
70 : 8

يَٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ قُل لِّمَن فِيٓ أَيۡدِيكُم مِّنَ ٱلۡأَسۡرَىٰٓ إِن يَعۡلَمِ ٱللَّهُ فِي قُلُوبِكُمۡ خَيۡرٗا يُؤۡتِكُمۡ خَيۡرٗا مِّمَّآ أُخِذَ مِنكُمۡ وَيَغۡفِرۡ لَكُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ

Ìwọ Ànábì, sọ fún àwọn tó ń bẹ lọ́wọ́ yín nínú àwọn ẹrú ogun pé, “Tí Allāhu bá mọ dáadáa kan nínú ọkàn yín, Ó máa fún yín ní ohun tó dára ju ohun tí wọ́n gbà lọ́wọ́ yín. Ó sì máa foríjìn yín. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Oníkẹ̀ẹ́.” info
التفاسير:

external-link copy
71 : 8

وَإِن يُرِيدُواْ خِيَانَتَكَ فَقَدۡ خَانُواْ ٱللَّهَ مِن قَبۡلُ فَأَمۡكَنَ مِنۡهُمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ

Tí wọ́n bá sì ń gbèrò ìjàǹbá sí ọ, wọ́n kúkú ti jàǹbá Allāhu ṣíwájú. Ó sì fún ọ lágbára lórí wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
72 : 8

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلَّذِينَ ءَاوَواْ وَّنَصَرُوٓاْ أُوْلَٰٓئِكَ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٖۚ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَلَمۡ يُهَاجِرُواْ مَا لَكُم مِّن وَلَٰيَتِهِم مِّن شَيۡءٍ حَتَّىٰ يُهَاجِرُواْۚ وَإِنِ ٱسۡتَنصَرُوكُمۡ فِي ٱلدِّينِ فَعَلَيۡكُمُ ٱلنَّصۡرُ إِلَّا عَلَىٰ قَوۡمِۭ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَهُم مِّيثَٰقٞۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ

Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, àti àwọn tó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; àwọn wọ̀nyẹn, apá kan wọn l’ọ̀rẹ́ apá kan (tó lè jogún ara wọn). Àwọn tó gbàgbọ́, tí wọn kò sì gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ níbì kan kan (tó lè mu yín jogún ara yín), títí wọn yóò fi gbé ìlú wọn jù sílẹ̀.[1] Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ yín (lórí ọ̀tá) nípa ẹ̀sìn, ìrànlọ́wọ́ náà di dandan fún yín àyàfi lórí ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. info

1. Ní ìbẹ̀rẹ̀ hijrah ṣíṣe sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ láti inú ẹbí kan fún ẹni tó ṣe hijrah. Àìṣe hijrah sì sọ ogún jíjẹ di èèwọ̀ láti inú ẹbí kan náà fún ẹni tí kò ṣe hijrah, wọn ìbáà dìjọ jẹ́ mùsùlùmí. Fífi hijrah sọ ogún jíjẹ di ẹ̀tọ́ sì wà bẹ́ẹ̀ títí wọ́n fi ṣí ìlú Mọkkah. Wọn kò si fi hijrah ṣíṣe pín ogún fún ẹnikẹ́ni mọ́ ní ìbámu sí āyah 75 nínú sūrah yìí. Lẹ́yìn náà, àwọn āyah ogún pípín fún àwọn ẹbí sọ̀kalẹ̀ nínú sūrah an-Nisā’.

التفاسير:

external-link copy
73 : 8

وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلِيَآءُ بَعۡضٍۚ إِلَّا تَفۡعَلُوهُ تَكُن فِتۡنَةٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَفَسَادٞ كَبِيرٞ

Àwọn aláìgbàgbọ́; apá kan wọn ni alátìlẹ́yìn apá kan. Àfi kí ẹ̀yin náà ṣe bẹ́ẹ̀ ni ìfòòró àti ìbàjẹ́ tó tóbi kò fi níí wà lórí ilẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
74 : 8

وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَهَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلَّذِينَ ءَاوَواْ وَّنَصَرُوٓاْ أُوْلَٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ حَقّٗاۚ لَّهُم مَّغۡفِرَةٞ وَرِزۡقٞ كَرِيمٞ

Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu àti àwọn tó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; ní ti òdodo àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni onígbàgbọ́ òdodo. Àforíjìn àti arísìkí alápọ̀n-ọ́nlé sì wà fún wọn info
التفاسير:

external-link copy
75 : 8

وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنۢ بَعۡدُ وَهَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ مَعَكُمۡ فَأُوْلَٰٓئِكَ مِنكُمۡۚ وَأُوْلُواْ ٱلۡأَرۡحَامِ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلَىٰ بِبَعۡضٖ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمُۢ

Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo lẹ́yìn (wọn), tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì jagun ẹ̀sìn pẹ̀lú yín, àwọn wọ̀nyẹn náà wà lára yín. Àti pé àwọn ìbátan, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ jùlọ sí apá kan (nípa ogún jíjẹ) nínú Tírà Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. info
التفاسير: