Vertaling van de betekenissen Edele Qur'an - Yoruba vertaling - Aboe Rahimah Mikail

Al-Fat'h

external-link copy
1 : 48

إِنَّا فَتَحۡنَا لَكَ فَتۡحٗا مُّبِينٗا

Dájúdájú Àwa ṣẹ́gun fún ọ ní ìṣẹ́gun tó fojú hàn info
التفاسير:

external-link copy
2 : 48

لِّيَغۡفِرَ لَكَ ٱللَّهُ مَا تَقَدَّمَ مِن ذَنۢبِكَ وَمَا تَأَخَّرَ وَيُتِمَّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكَ وَيَهۡدِيَكَ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا

nítorí kí Allāhu lè ṣàforíjìn ohun tí ó ṣíwájú nínú àṣìṣe rẹ àti ohun tí ó kẹ́yìn (nínú rẹ̀),[1] àti nítorí kí Ó lè ṣàṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ lé ọ lórí àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām), info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Gọ̄fir; 40:55.

التفاسير:

external-link copy
3 : 48

وَيَنصُرَكَ ٱللَّهُ نَصۡرًا عَزِيزًا

àti nítorí kí Allāhu lè ṣàrànṣe fún ọ ní àrànṣe tó lágbára. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 48

هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ ٱلسَّكِينَةَ فِي قُلُوبِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ لِيَزۡدَادُوٓاْ إِيمَٰنٗا مَّعَ إِيمَٰنِهِمۡۗ وَلِلَّهِ جُنُودُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا

Òun ni Ẹni tí Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ sínú ọkàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí wọ́n lè lékún ní ìgbàgbọ́ sí ìgbàgbọ́ wọn. Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 48

لِّيُدۡخِلَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ جَنَّٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا وَيُكَفِّرَ عَنۡهُمۡ سَيِّـَٔاتِهِمۡۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عِندَ ٱللَّهِ فَوۡزًا عَظِيمٗا

(Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn) nítorí kí Ó lè mú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀, olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀, àti nítorí kí Ó lè pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ èrèǹjẹ ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 48

وَيُعَذِّبَ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقَٰتِ وَٱلۡمُشۡرِكِينَ وَٱلۡمُشۡرِكَٰتِ ٱلظَّآنِّينَ بِٱللَّهِ ظَنَّ ٱلسَّوۡءِۚ عَلَيۡهِمۡ دَآئِرَةُ ٱلسَّوۡءِۖ وَغَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ وَلَعَنَهُمۡ وَأَعَدَّ لَهُمۡ جَهَنَّمَۖ وَسَآءَتۡ مَصِيرٗا

Àti nítorí kí Ó lè fìyà jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin, pẹ̀lú àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin àti àwọn ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin, àwọn eléròkérò nípa Allāhu ní ti èrò aburú. Àpadàsí aburú ń bẹ fún wọn. Allāhu ti bínú sí wọn. Ó ti ṣẹ́bi lé wọn. Ó sì ti pèsè iná Jahanamọ sílẹ̀ dè wọ́n. Ó sì burú ní ìkángun. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 48

وَلِلَّهِ جُنُودُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا

Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 48

إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ شَٰهِدٗا وَمُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا

Dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ info
التفاسير:

external-link copy
9 : 48

لِّتُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَتُعَزِّرُوهُ وَتُوَقِّرُوهُۚ وَتُسَبِّحُوهُ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلًا

nítorí kí ẹ lè ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti (nítorí kí) ẹ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún (Òjíṣẹ́ náà) àti nítorí kí ẹ lè pàtàkì rẹ̀, àti nítorí kí ẹ lè ṣàfọ̀mọ́ fún (Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́. info
التفاسير: