1. Kíyè sí gbólóhùn yìí dáradára “tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo”. Ó ń túmọ̀ sí pé, èyíkéyìí iṣẹ́ rere tí Ànábì kan bá mú wá fún ìjọ rẹ̀, bí ẹni tí kò bá ní ìgbàgbọ́ òdodo ’Islām bá ṣe iṣẹ́ rere náà fún gbogbo ìṣẹ̀mí ayé rẹ̀, Allāhu kò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí náà, májẹ̀mu kan lọ́tọ̀ ni ìgbàgbọ́ òdodo ’Islām jẹ́ lórí ṣíṣe iṣẹ́ rere. 2. Ìyẹn ni pé, ẹ̀san rere tó máa jẹ́ àwọn ìjẹ-ìmu àti àwọn ìgbádùn oníran-ànran ní ọ̀run fún àwọn olùṣe-rere máa pọ̀ gan-an jaburata.