Vertaling van de betekenissen Edele Qur'an - Yoruba vertaling - Aboe Rahimah Mikail

Al-Fur'qaan

external-link copy
1 : 25

تَبَارَكَ ٱلَّذِي نَزَّلَ ٱلۡفُرۡقَانَ عَلَىٰ عَبۡدِهِۦ لِيَكُونَ لِلۡعَٰلَمِينَ نَذِيرًا

Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó sọ ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣe ìpínyà láààrin òdodo àti irọ́) kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀ nítorí kí ó lè jẹ́ olùkìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 25

ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلَمۡ يَتَّخِذۡ وَلَدٗا وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٞ فِي ٱلۡمُلۡكِ وَخَلَقَ كُلَّ شَيۡءٖ فَقَدَّرَهُۥ تَقۡدِيرٗا

(Òun ni) Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò mú ẹnì kan kan ní ọmọ. Kò sí akẹgbẹ́ fún Un nínú ìjọba (Rẹ̀). Ó dá gbogbo n̄ǹkan. Ó sì yan òdíwọ̀n (ìrísí, ìṣẹ̀mí àti àyànmọ́) fún un níwọ̀n-níwọ̀n. info
التفاسير: