1. “Muzdajar” wáàsí tó le tó kún fún ìṣẹ̀rùbà àti àpẹ̀ẹrẹ ìjìyà tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn ọ̀tá òdodo.
1. Ìyẹn ni pé, wọ́n fi ohùn líle kọ òdodo sílẹ̀ fún Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní kíkọ̀ àlésá-sẹ́yìn fún wọn nípasẹ̀ sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i, híhalẹ̀ mọ̀ ọn, dídúnkokò mọ́ ọn nítorí kí ó lè máa wò wọ́n níran.
1. Ìyẹn ni pé, a máa lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún nínú sàréè, àmọ́ láààrin ká ṣẹ́jú ká lajú, gbogbo ẹ̀dá máa jí dìde láti inú sàréè wọn.