ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
28 : 54

وَنَبِّئۡهُمۡ أَنَّ ٱلۡمَآءَ قِسۡمَةُۢ بَيۡنَهُمۡۖ كُلُّ شِرۡبٖ مُّحۡتَضَرٞ

Kí o sì fún wọn ní ìró pé dájúdájú pípín ni omi láààrin wọn. Gbogbo ìpín omi sì wà fún ẹni tí ó bá kàn láti wá sí odò. info
التفاسير:

external-link copy
29 : 54

فَنَادَوۡاْ صَاحِبَهُمۡ فَتَعَاطَىٰ فَعَقَرَ

Wọ́n pe ẹni wọn. Ó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ nawọ́ mú (ràkúnmí náà mọ́lẹ̀). Ó sì pa á. info
التفاسير:

external-link copy
30 : 54

فَكَيۡفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ

Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)? info
التفاسير:

external-link copy
31 : 54

إِنَّآ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ فَكَانُواْ كَهَشِيمِ ٱلۡمُحۡتَظِرِ

Dájúdájú Àwa rán igbe kan ṣoṣo sí wọn. Wọ́n sì dà bí koríko gbígbẹ tí àgbẹ̀ dáná sun. info
التفاسير:

external-link copy
32 : 54

وَلَقَدۡ يَسَّرۡنَا ٱلۡقُرۡءَانَ لِلذِّكۡرِ فَهَلۡ مِن مُّدَّكِرٖ

Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí? info
التفاسير:

external-link copy
33 : 54

كَذَّبَتۡ قَوۡمُ لُوطِۭ بِٱلنُّذُرِ

Ìjọ Lūt pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́. info
التفاسير:

external-link copy
34 : 54

إِنَّآ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ حَاصِبًا إِلَّآ ءَالَ لُوطٖۖ نَّجَّيۡنَٰهُم بِسَحَرٖ

Dájúdájú Àwa fi òkúta iná ránṣẹ́ sí wọn àfi ará ilé Lūt, tí A gbàlà ní àsìkò sààrì. info
التفاسير:

external-link copy
35 : 54

نِّعۡمَةٗ مِّنۡ عِندِنَاۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي مَن شَكَرَ

(Ó jẹ́) ìkẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹni tó bá dúpẹ́ (fún Wa). info
التفاسير:

external-link copy
36 : 54

وَلَقَدۡ أَنذَرَهُم بَطۡشَتَنَا فَتَمَارَوۡاْ بِٱلنُّذُرِ

Ó kúkú fi ìgbámú Wa ṣe ìkìlọ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ja àwọn ìkìlọ̀ níyàn. info
التفاسير:

external-link copy
37 : 54

وَلَقَدۡ رَٰوَدُوهُ عَن ضَيۡفِهِۦ فَطَمَسۡنَآ أَعۡيُنَهُمۡ فَذُوقُواْ عَذَابِي وَنُذُرِ

Wọ́n kúkú làkàkà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti bá àwọn aléjò rẹ̀ ṣèbàjẹ́. Nítorí náà, A fọ́ ojú wọn. Ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò. info
التفاسير:

external-link copy
38 : 54

وَلَقَدۡ صَبَّحَهُم بُكۡرَةً عَذَابٞ مُّسۡتَقِرّٞ

Àti pé dájúdájú ìyà gbére ni wọ́n mọ́júmọ́ sínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù. info
التفاسير:

external-link copy
39 : 54

فَذُوقُواْ عَذَابِي وَنُذُرِ

Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi wò. info
التفاسير:

external-link copy
40 : 54

وَلَقَدۡ يَسَّرۡنَا ٱلۡقُرۡءَانَ لِلذِّكۡرِ فَهَلۡ مِن مُّدَّكِرٖ

Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí? info
التفاسير:

external-link copy
41 : 54

وَلَقَدۡ جَآءَ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ ٱلنُّذُرُ

Dájúdájú àwọn ìkìlọ̀ dé bá àwọn ènìyàn Fir‘aon. info
التفاسير:

external-link copy
42 : 54

كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا كُلِّهَا فَأَخَذۡنَٰهُمۡ أَخۡذَ عَزِيزٖ مُّقۡتَدِرٍ

Wọ́n pe gbogbo àwọn āyah Wa ní irọ́ pátápátá. A sì gbá wọn mú ní ìgbámú (tí) Alágbára, Olùkápá (máa ń gbá ẹ̀dá mú). info
التفاسير:

external-link copy
43 : 54

أَكُفَّارُكُمۡ خَيۡرٞ مِّنۡ أُوْلَٰٓئِكُمۡ أَمۡ لَكُم بَرَآءَةٞ فِي ٱلزُّبُرِ

Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ (nínú) yín l’ó lóore ju àwọn wọ̀nyẹn (tí wọ́n ti parẹ́ bọ́ sẹ́yìn) ni tàbí ẹ̀yin ní ìmóríbọ́ kan nínú ìpín-ìpín Tírà (pé ẹ̀yin kò níí jìyà)? info
التفاسير:

external-link copy
44 : 54

أَمۡ يَقُولُونَ نَحۡنُ جَمِيعٞ مُّنتَصِرٞ

Tàbí wọ́n ń wí pé: “Àwa wà papọ̀ tí a óò ranra wa lọ́wọ́ láti borí (Òjíṣẹ́)” info
التفاسير:

external-link copy
45 : 54

سَيُهۡزَمُ ٱلۡجَمۡعُ وَيُوَلُّونَ ٱلدُّبُرَ

A máa fọ́ àkójọ náà lógun. Wọn sì máa fẹsẹ̀ fẹ́ẹ lójú ogun. info
التفاسير:

external-link copy
46 : 54

بَلِ ٱلسَّاعَةُ مَوۡعِدُهُمۡ وَٱلسَّاعَةُ أَدۡهَىٰ وَأَمَرُّ

Àmọ́ sá, Àkókò náà ni ọjọ́ àdéhùn wọn. Àkókò náà burú jùlọ. Ó sì korò jùlọ. info
التفاسير:

external-link copy
47 : 54

إِنَّ ٱلۡمُجۡرِمِينَ فِي ضَلَٰلٖ وَسُعُرٖ

Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wà nínú ìṣìnà àti wàhálà. info
التفاسير:

external-link copy
48 : 54

يَوۡمَ يُسۡحَبُونَ فِي ٱلنَّارِ عَلَىٰ وُجُوهِهِمۡ ذُوقُواْ مَسَّ سَقَرَ

Ní ọjọ́ tí A óò dojú wọn bolẹ̀ wọ inú Iná, (A ó sì sọ pé): Ẹ tọ́ ìfọwọ́bà Iná wò. info
التفاسير:

external-link copy
49 : 54

إِنَّا كُلَّ شَيۡءٍ خَلَقۡنَٰهُ بِقَدَرٖ

Dájúdájú A ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú kádàrá. info
التفاسير: