ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
7 : 54

خُشَّعًا أَبۡصَٰرُهُمۡ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ كَأَنَّهُمۡ جَرَادٞ مُّنتَشِرٞ

Ojú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 54

مُّهۡطِعِينَ إِلَى ٱلدَّاعِۖ يَقُولُ ٱلۡكَٰفِرُونَ هَٰذَا يَوۡمٌ عَسِرٞ

Wọn yó sì máa yára lọ sí ọ̀dọ̀ olùpèpè náà. Àwọn aláìgbàgbọ́ yó sì wí pé: “Èyí ni ọjọ́ ìṣòro.” info
التفاسير:

external-link copy
9 : 54

۞ كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ فَكَذَّبُواْ عَبۡدَنَا وَقَالُواْ مَجۡنُونٞ وَٱزۡدُجِرَ

Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè ni.” Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.[1] info

1. Ìyẹn ni pé, wọ́n fi ohùn líle kọ òdodo sílẹ̀ fún Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní kíkọ̀ àlésá-sẹ́yìn fún wọn nípasẹ̀ sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i, híhalẹ̀ mọ̀ ọn, dídúnkokò mọ́ ọn nítorí kí ó lè máa wò wọ́n níran.

التفاسير:

external-link copy
10 : 54

فَدَعَا رَبَّهُۥٓ أَنِّي مَغۡلُوبٞ فَٱنتَصِرۡ

Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Bá mi gbẹ̀san.” info
التفاسير:

external-link copy
11 : 54

فَفَتَحۡنَآ أَبۡوَٰبَ ٱلسَّمَآءِ بِمَآءٖ مُّنۡهَمِرٖ

Nítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi tó lágbára. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 54

وَفَجَّرۡنَا ٱلۡأَرۡضَ عُيُونٗا فَٱلۡتَقَى ٱلۡمَآءُ عَلَىٰٓ أَمۡرٖ قَدۡ قُدِرَ

A tún mú àwọn odò ṣàn jáde láti inú ilẹ̀. Omi (sánmọ̀) pàdé (omi ilẹ̀) pẹ̀lú àṣẹ tí A ti kọ (lé wọn lórí). info
التفاسير:

external-link copy
13 : 54

وَحَمَلۡنَٰهُ عَلَىٰ ذَاتِ أَلۡوَٰحٖ وَدُسُرٖ

A sì gbé (Ànábì) Nūh gun ọkọ̀ onípákó, ọkọ̀ eléṣòó, info
التفاسير:

external-link copy
14 : 54

تَجۡرِي بِأَعۡيُنِنَا جَزَآءٗ لِّمَن كَانَ كُفِرَ

tí ó ń rìn (lórí omi) lójú Wa. (Ó jẹ́) ẹ̀san nítorí ẹni tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
15 : 54

وَلَقَد تَّرَكۡنَٰهَآ ءَايَةٗ فَهَلۡ مِن مُّدَّكِرٖ

Dájúdájú A ṣẹ́ ẹ kù (tí A fi ṣe) àmì. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí? info
التفاسير:

external-link copy
16 : 54

فَكَيۡفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ

Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)? info
التفاسير:

external-link copy
17 : 54

وَلَقَدۡ يَسَّرۡنَا ٱلۡقُرۡءَانَ لِلذِّكۡرِ فَهَلۡ مِن مُّدَّكِرٖ

Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí? info
التفاسير:

external-link copy
18 : 54

كَذَّبَتۡ عَادٞ فَكَيۡفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ

Ìran ‘Ād pé òdodo ní irọ́. Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)? info
التفاسير:

external-link copy
19 : 54

إِنَّآ أَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا صَرۡصَرٗا فِي يَوۡمِ نَحۡسٖ مُّسۡتَمِرّٖ

Dájúdájú Àwa rán atẹ́gùn líle sí wọn ní ọjọ́ burúkú kan tó ń tẹ̀ síwájú.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Fussilat; 41:16.

التفاسير:

external-link copy
20 : 54

تَنزِعُ ٱلنَّاسَ كَأَنَّهُمۡ أَعۡجَازُ نَخۡلٖ مُّنقَعِرٖ

Ó ń fa àwọn ènìyàn tu bí ẹni pé kùkùté igi ọ̀pẹ tí wọ́n fà tu tegbòtegbò ni wọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
21 : 54

فَكَيۡفَ كَانَ عَذَابِي وَنُذُرِ

Báwo ni ìyà Mi àti ìkìlọ̀ Mi ti rí ná (lára wọn)? info
التفاسير:

external-link copy
22 : 54

وَلَقَدۡ يَسَّرۡنَا ٱلۡقُرۡءَانَ لِلذِّكۡرِ فَهَلۡ مِن مُّدَّكِرٖ

Dájúdájú A ṣe al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn fún ṣíṣe ìrántí. Ǹjẹ́ olùrántí wà báyìí bí? info
التفاسير:

external-link copy
23 : 54

كَذَّبَتۡ ثَمُودُ بِٱلنُّذُرِ

Ìjọ Thamūd pe àwọn ìkìlọ̀ ní irọ́. info
التفاسير:

external-link copy
24 : 54

فَقَالُوٓاْ أَبَشَرٗا مِّنَّا وَٰحِدٗا نَّتَّبِعُهُۥٓ إِنَّآ إِذٗا لَّفِي ضَلَٰلٖ وَسُعُرٍ

Wọ́n wí pé: “Ṣé abara kan, ẹnì kan ṣoṣo nínú wa ni a óò máa tẹ̀lé. (Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀) nígbà náà dájúdájú àwa ti wà nínú ìṣìnà àti wàhálà. info
التفاسير:

external-link copy
25 : 54

أَءُلۡقِيَ ٱلذِّكۡرُ عَلَيۡهِ مِنۢ بَيۡنِنَا بَلۡ هُوَ كَذَّابٌ أَشِرٞ

Ṣé òun ni wọ́n sọ tírà ìrántí kalẹ̀ fún láààrin wa? Rárá o, òpùrọ́ onígbèéraga ni.” info
التفاسير:

external-link copy
26 : 54

سَيَعۡلَمُونَ غَدٗا مَّنِ ٱلۡكَذَّابُ ٱلۡأَشِرُ

Ní ọ̀la ni wọn yóò mọ ta ni òpùrọ́ onígbèéraga. info
التفاسير:

external-link copy
27 : 54

إِنَّا مُرۡسِلُواْ ٱلنَّاقَةِ فِتۡنَةٗ لَّهُمۡ فَٱرۡتَقِبۡهُمۡ وَٱصۡطَبِرۡ

Dájúdájú Àwa máa rán abo ràkúnmí sí wọn; (ó máa jẹ́) àdánwò fún wọn. Nítorí náà, máa wò wọ́n níran ná, kí o sì ṣe sùúrù.[1] info

1. Ṣe sùúrù láì níí fi ẹjọ́ wọn sùn mọ́.

التفاسير: