ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
73 : 21

وَجَعَلۡنَٰهُمۡ أَئِمَّةٗ يَهۡدُونَ بِأَمۡرِنَا وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَيۡهِمۡ فِعۡلَ ٱلۡخَيۡرَٰتِ وَإِقَامَ ٱلصَّلَوٰةِ وَإِيتَآءَ ٱلزَّكَوٰةِۖ وَكَانُواْ لَنَا عَٰبِدِينَ

A ṣe wọ́n ní aṣíwájú tó ń tọ́ àwọn ènìyàn sí ọ̀nà pẹ̀lú àṣẹ Wa. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí wọn nípa ṣíṣe iṣẹ́ rere, ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Wọ́n sì jẹ́ olùjọ́sìn fún Wa. info
التفاسير:

external-link copy
74 : 21

وَلُوطًا ءَاتَيۡنَٰهُ حُكۡمٗا وَعِلۡمٗا وَنَجَّيۡنَٰهُ مِنَ ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلَّتِي كَانَت تَّعۡمَلُ ٱلۡخَبَٰٓئِثَۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمَ سَوۡءٖ فَٰسِقِينَ

(Ẹ rántí Ànábì) Lūt. A fún un ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì gbà á là nínú ìlú tí wọ́n ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ burúkú. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú, òbìlẹ̀jẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
75 : 21

وَأَدۡخَلۡنَٰهُ فِي رَحۡمَتِنَآۖ إِنَّهُۥ مِنَ ٱلصَّٰلِحِينَ

A sì mú un wọ inú ìkẹ́ Wa. Dájúdájú ó wà nínú àwọn ẹni rere. info
التفاسير:

external-link copy
76 : 21

وَنُوحًا إِذۡ نَادَىٰ مِن قَبۡلُ فَٱسۡتَجَبۡنَا لَهُۥ فَنَجَّيۡنَٰهُ وَأَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلۡكَرۡبِ ٱلۡعَظِيمِ

(Ẹ rántí Ànábì) Nūh, nígbà tí ó pe ìpè ṣíwájú. A sì jẹ́pè rẹ̀. A sì gba òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ là nínú ìbànújẹ́ ńlá. info
التفاسير:

external-link copy
77 : 21

وَنَصَرۡنَٰهُ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَآۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمَ سَوۡءٖ فَأَغۡرَقۡنَٰهُمۡ أَجۡمَعِينَ

A sì ṣàrànṣe fún un lórí àwọn ènìyàn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ burúkú. A sì tẹ̀ wọ́n rì pátápátá. info
التفاسير:

external-link copy
78 : 21

وَدَاوُۥدَ وَسُلَيۡمَٰنَ إِذۡ يَحۡكُمَانِ فِي ٱلۡحَرۡثِ إِذۡ نَفَشَتۡ فِيهِ غَنَمُ ٱلۡقَوۡمِ وَكُنَّا لِحُكۡمِهِمۡ شَٰهِدِينَ

(Ẹ rántí Ànábì) Dāwūd àti (Ànábì) Sulaemọ̄n, (rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ń ṣe ìdájọ́ lórí (ọ̀rọ̀) oko, nígbà tí àgùtàn ìjọ kan jẹko wọ inú oko náà. Àwa sì jẹ́ Olùjẹ́rìí sí ìdájọ́ wọn. info
التفاسير:

external-link copy
79 : 21

فَفَهَّمۡنَٰهَا سُلَيۡمَٰنَۚ وَكُلًّا ءَاتَيۡنَا حُكۡمٗا وَعِلۡمٗاۚ وَسَخَّرۡنَا مَعَ دَاوُۥدَ ٱلۡجِبَالَ يُسَبِّحۡنَ وَٱلطَّيۡرَۚ وَكُنَّا فَٰعِلِينَ

A sì fún (Ànábì) Sulaemọ̄n ní àgbọ́yé rẹ̀. Àti pé ìkọ̀ọ̀kan (wọn) ni A fún ní ipò Ànábì àti ìmọ̀. A sì tẹ àwọn àpáta àti ẹyẹ ba; wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) pẹ̀lú (Ànábì) Dāwūd. Àwa l’A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
80 : 21

وَعَلَّمۡنَٰهُ صَنۡعَةَ لَبُوسٖ لَّكُمۡ لِتُحۡصِنَكُم مِّنۢ بَأۡسِكُمۡۖ فَهَلۡ أَنتُمۡ شَٰكِرُونَ

A tún fún un ní ìmọ̀ nípa ṣíṣe ẹ̀wù irin fún yín nítorí kí ó lè jẹ́ odi ìṣọ́ fún yín níbi ogun yín. Nítorí náà, ǹjẹ́ olùdúpẹ́ (fún Allāhu) ni ẹ̀yin bí? info
التفاسير:

external-link copy
81 : 21

وَلِسُلَيۡمَٰنَ ٱلرِّيحَ عَاصِفَةٗ تَجۡرِي بِأَمۡرِهِۦٓ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَاۚ وَكُنَّا بِكُلِّ شَيۡءٍ عَٰلِمِينَ

A sì tẹ atẹ́gùn líle lórí ba fún (Ànábì) Sulaemọ̄n. Ó ń gbé e lọ pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀ sórí ilẹ̀ tí A fi ìbùkún sí. A sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. info
التفاسير: