ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
45 : 21

قُلۡ إِنَّمَآ أُنذِرُكُم بِٱلۡوَحۡيِۚ وَلَا يَسۡمَعُ ٱلصُّمُّ ٱلدُّعَآءَ إِذَا مَا يُنذَرُونَ

Sọ pé: “Ìmísí ni mo fi ń kìlọ̀ fún yín. Àwọn adití kò sì níí gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá ń kìlọ̀ fún wọn.” info
التفاسير:

external-link copy
46 : 21

وَلَئِن مَّسَّتۡهُمۡ نَفۡحَةٞ مِّنۡ عَذَابِ رَبِّكَ لَيَقُولُنَّ يَٰوَيۡلَنَآ إِنَّا كُنَّا ظَٰلِمِينَ

Àti pé dájúdájú tí abala kan nínú ìyà Olúwa rẹ bá fọwọ́ bà wọ́n, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò; dájúdájú àwa jẹ́ alábòsí.” info
التفاسير:

external-link copy
47 : 21

وَنَضَعُ ٱلۡمَوَٰزِينَ ٱلۡقِسۡطَ لِيَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ فَلَا تُظۡلَمُ نَفۡسٞ شَيۡـٔٗاۖ وَإِن كَانَ مِثۡقَالَ حَبَّةٖ مِّنۡ خَرۡدَلٍ أَتَيۡنَا بِهَاۗ وَكَفَىٰ بِنَا حَٰسِبِينَ

A máa gbé àwọn òṣùwọ̀n déédé kalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Nítorí náà, wọn kò níí ṣe àbòsí kiní kan fún ẹ̀mí kan. Kí (iṣẹ́) jẹ́ ìwọ̀n èso kardal (bín-íntín), A máa mú un wá. A sì tó ní Olùṣírò. info
التفاسير:

external-link copy
48 : 21

وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ ٱلۡفُرۡقَانَ وَضِيَآءٗ وَذِكۡرٗا لِّلۡمُتَّقِينَ

Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā àti (Ànábì) Hārūn ní ọ̀rọ̀-ìpínyà (ohun tó ń ṣòpínyà láààrin òdodo àti irọ́), ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).[1] info

1. Ọ̀rọ̀-ìpínyà, ìmọ́lẹ̀ àti ìrántí nínú āyah yìí dúró fún àwọn ìròyìn tó wà lára tírà kan ṣoṣo tí Allāhu - tó ga jùlọ - fún Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Tírà náà ni at-Taorāt.

التفاسير:

external-link copy
49 : 21

ٱلَّذِينَ يَخۡشَوۡنَ رَبَّهُم بِٱلۡغَيۡبِ وَهُم مِّنَ ٱلسَّاعَةِ مُشۡفِقُونَ

(Àwọn ni) àwọn tó ń páyà Olúwa wọn ní ìkọ̀kọ̀. Olùpáyà sì ni wọ́n nípa Àkókò náà. info
التفاسير:

external-link copy
50 : 21

وَهَٰذَا ذِكۡرٞ مُّبَارَكٌ أَنزَلۡنَٰهُۚ أَفَأَنتُمۡ لَهُۥ مُنكِرُونَ

Èyí sì ni ìrántí oníbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Ṣé ẹ̀yin yóò takò ó ni? info
التفاسير:

external-link copy
51 : 21

۞ وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَآ إِبۡرَٰهِيمَ رُشۡدَهُۥ مِن قَبۡلُ وَكُنَّا بِهِۦ عَٰلِمِينَ

Dájúdájú A ti fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm ní ìmọ̀nà tirẹ̀ ṣíwájú (kí ó tó dàgbà). Àwa sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
52 : 21

إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦ مَا هَٰذِهِ ٱلتَّمَاثِيلُ ٱلَّتِيٓ أَنتُمۡ لَهَا عَٰكِفُونَ

(Rántí) nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀ pé: “Kí ni àwọn ère wọ̀nyí tí ẹ̀ ń dúró tì, tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ṣe jẹ́ ná?” info
التفاسير:

external-link copy
53 : 21

قَالُواْ وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا لَهَا عَٰبِدِينَ

Wọ́n wí pé: “A bá àwọn bàbá wa tí wọ́n ń jọ́sìn fún wọn ni.” info
التفاسير:

external-link copy
54 : 21

قَالَ لَقَدۡ كُنتُمۡ أَنتُمۡ وَءَابَآؤُكُمۡ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ

Ó sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.” info
التفاسير:

external-link copy
55 : 21

قَالُوٓاْ أَجِئۡتَنَا بِٱلۡحَقِّ أَمۡ أَنتَ مِنَ ٱللَّٰعِبِينَ

Wọ́n wí pé: “Ṣé o mú òdodo wá fún wa ni tàbí ìwọ wà nínú àwọn ẹlẹ́fẹ̀.” info
التفاسير:

external-link copy
56 : 21

قَالَ بَل رَّبُّكُمۡ رَبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ ٱلَّذِي فَطَرَهُنَّ وَأَنَا۠ عَلَىٰ ذَٰلِكُم مِّنَ ٱلشَّٰهِدِينَ

Ó sọ pé: “Rárá. Olúwa yin ni Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; Ẹni tí Ó pílẹ̀ ìṣẹ̀dá wọn. Èmi sì wà nínú àwọn ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn. info
التفاسير:

external-link copy
57 : 21

وَتَٱللَّهِ لَأَكِيدَنَّ أَصۡنَٰمَكُم بَعۡدَ أَن تُوَلُّواْ مُدۡبِرِينَ

Àti pé mo fi Allāhu búra, dájúdájú mo máa dète sí àwọn òrìṣà yín lẹ́yìn tí ẹ bá pẹ̀yìn dà, tí ẹ lọ.” info
التفاسير: