1. Ìtúmọ̀ méjì ló wà fún “katọyyi-ssijilli lilkutub”. Ìkíní: bíi kíká ewé tírà. Ìkejì: bíí kíká tí mọlāika tí ń jẹ́ Sijill máa ń ká àwọn tírà iṣẹ́ ẹ̀dá nílẹ̀ níkété tí ó bá ṣíwọ́ iṣẹ́.
1. Ìtúmọ̀ yìí wà ní ìbámu sí sūrah az-Zumọr; 39:74.
1. Ìtúmọ̀ méjì ló wà fún “balāg” nínú āyah yìí. Ìtúmọ̀ kejì nìyí, Dájúdájú “ohun tí ó máa mú ẹ̀dá gúnlẹ̀ síbi ìyọ́nú Allāhu” wà nínú (al-Ƙur’ān) yìí fún ìjọ tó ń jọ́sìn (fún Allāhu ní ọ̀nà òdodo). (Tafsīr ’Adwā’il-bayān li Ṣinƙītiy)
1. Ìyẹn ni pé, kí Allāhu Aláàánú ṣàánú wà lórí àwọn irọ́ tí àwọn aláìgbàgbọ́ wọ̀nyí ń pa mọ́ Allāhu nítorí pé, nígbà tí ìyà rẹ̀ bá dé nílé ayé yìí, aláìṣẹ̀ yóò pín nínú rẹ̀.