ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
91 : 15

ٱلَّذِينَ جَعَلُواْ ٱلۡقُرۡءَانَ عِضِينَ

àwọn tí wọ́n sọ al-Ƙur’ān di ìpínkúpìn-ín,[1] info

1. Ẹ wo bí àwọn aláìgbàgbọ́ ṣe pín al-Ƙur’ān sí ìpínkúpìn-ín nínú sūrah al-’Anbiyā’; 21:3-5.

التفاسير:

external-link copy
92 : 15

فَوَرَبِّكَ لَنَسۡـَٔلَنَّهُمۡ أَجۡمَعِينَ

Olúwa rẹ fi Ara Rẹ̀ búra fún ọ pé, A máa bi gbogbo wọn ní ìbéèrè info
التفاسير:

external-link copy
93 : 15

عَمَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ

nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
94 : 15

فَٱصۡدَعۡ بِمَا تُؤۡمَرُ وَأَعۡرِضۡ عَنِ ٱلۡمُشۡرِكِينَ

Nítorí náà, kéde n̄ǹkan tí A pa láṣẹ fún ọ. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ. info
التفاسير:

external-link copy
95 : 15

إِنَّا كَفَيۡنَٰكَ ٱلۡمُسۡتَهۡزِءِينَ

Dájúdájú Àwa yóò tó ọ (níbi aburú) àwọn oníyẹ̀yẹ́, info
التفاسير:

external-link copy
96 : 15

ٱلَّذِينَ يَجۡعَلُونَ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَۚ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ

àwọn tó ń mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu. Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
97 : 15

وَلَقَدۡ نَعۡلَمُ أَنَّكَ يَضِيقُ صَدۡرُكَ بِمَا يَقُولُونَ

Àwa kúkú ti mọ̀ pé dájúdájú ohun tí wọ́n ń wí ń kó ìnira bá ọ. info
التفاسير:

external-link copy
98 : 15

فَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ وَكُن مِّنَ ٱلسَّٰجِدِينَ

Nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ.[1] Kí o sì wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀ (fún Un). info

1. Ìyẹn ni pé, ṣe àfọ̀mọ́ Allāhu kúrò níbi gbogbo àdínkù àti àbùkù, kí o sì yìn Ín lógo pé, O pé tán pátápátá.

التفاسير:

external-link copy
99 : 15

وَٱعۡبُدۡ رَبَّكَ حَتَّىٰ يَأۡتِيَكَ ٱلۡيَقِينُ

Jọ́sìn fún Olúwa rẹ títí àmọ̀dájú (ìyẹn, ikú) yóò fi dé bá ọ. info
التفاسير: