ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
71 : 15

قَالَ هَٰٓؤُلَآءِ بَنَاتِيٓ إِن كُنتُمۡ فَٰعِلِينَ

Ó sọ pé: “Àwọn ọmọbìnrin mi nìwọ̀nyí, tí ẹ bá ní n̄ǹkan tí ẹ fẹ́ (fi wọ́n) ṣe.”[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Hūd; 11:78.

التفاسير:

external-link copy
72 : 15

لَعَمۡرُكَ إِنَّهُمۡ لَفِي سَكۡرَتِهِمۡ يَعۡمَهُونَ

(Allāhu sọ pé): “Mo fi ìṣẹ̀mí ìwọ (Ànábì Muhammad) búra;[1] dájúdájú wọ́n kúkú wà nínú ìṣìnà àti àìmọ̀kan wọn, tí wọ́n ń pa rìdàrìdà.” info

1. Ti Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - ni kí Ó fi ohun tí Ó bá fẹ́ búra.

التفاسير:

external-link copy
73 : 15

فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّيۡحَةُ مُشۡرِقِينَ

Nítorí náà, ohùn igbe mú wọn nígbà tí òòrùn òwúrọ̀ yọ sí wọn. info
التفاسير:

external-link copy
74 : 15

فَجَعَلۡنَا عَٰلِيَهَا سَافِلَهَا وَأَمۡطَرۡنَا عَلَيۡهِمۡ حِجَارَةٗ مِّن سِجِّيلٍ

A sì sọ òkè ìlú wọn di ìsàlẹ̀ rẹ̀ (ìlú wọ́n dojú bolẹ̀). A tún rọ òjò òkúta amọ̀ (sísun) lé wọn lórí. info
التفاسير:

external-link copy
75 : 15

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّلۡمُتَوَسِّمِينَ

Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn alárìíwòye. info
التفاسير:

external-link copy
76 : 15

وَإِنَّهَا لَبِسَبِيلٖ مُّقِيمٍ

Dájúdájú (ìlú náà) kúkú wà lójú ọ̀nà (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀). info
التفاسير:

external-link copy
77 : 15

إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ

Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
78 : 15

وَإِن كَانَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡأَيۡكَةِ لَظَٰلِمِينَ

Àwọn ará ’Aekah[1] náà jẹ́ alábòsí. info

1. ’Aekah tún túmọ̀ sí igbó. Ìyẹn ni pé, ìlú tí ó wà nínú igbó. Ará ’Aekah ni ìjọ Ànábì Ṣu‘aeb - kí ọlà Allāhu máa bá a -.

التفاسير:

external-link copy
79 : 15

فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ وَإِنَّهُمَا لَبِإِمَامٖ مُّبِينٖ

A sì gbẹ́san lára wọn. Dájújájú àwọn ìlú méjèèjì ló kúkú wà lójú ọ̀nà gban̄gba (tí ẹ̀ ń tọ̀ lọ tọ̀ bọ̀). info
التفاسير:

external-link copy
80 : 15

وَلَقَدۡ كَذَّبَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡحِجۡرِ ٱلۡمُرۡسَلِينَ

Dájúdájú àwọn ará Ihò àpáta pe àwọn Òjíṣẹ́ ní òpùrọ́. info
التفاسير:

external-link copy
81 : 15

وَءَاتَيۡنَٰهُمۡ ءَايَٰتِنَا فَكَانُواْ عَنۡهَا مُعۡرِضِينَ

A sì fún wọn ní àwọn àmì Wa. Àmọ́ wọ́n gbúnrí kúrò níbẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
82 : 15

وَكَانُواْ يَنۡحِتُونَ مِنَ ٱلۡجِبَالِ بُيُوتًا ءَامِنِينَ

Wọ́n máa ń gbẹ́ àwọn ilé ìgbé ìfàyàbalẹ̀ sínú àwọn àpáta. info
التفاسير:

external-link copy
83 : 15

فَأَخَذَتۡهُمُ ٱلصَّيۡحَةُ مُصۡبِحِينَ

Ohùn igbe sì mú wọn nígbà tí wọ́n mọ́júmọ́. info
التفاسير:

external-link copy
84 : 15

فَمَآ أَغۡنَىٰ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ

Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ kò sì rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ (níbi ìyà). info
التفاسير:

external-link copy
85 : 15

وَمَا خَلَقۡنَا ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَمَا بَيۡنَهُمَآ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۗ وَإِنَّ ٱلسَّاعَةَ لَأٓتِيَةٞۖ فَٱصۡفَحِ ٱلصَّفۡحَ ٱلۡجَمِيلَ

A kò ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀, ilẹ̀ àti n̄ǹkan tó wà láààrin àwọn méjèèjì bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú Àkókò náà máa dé. Nítorí náà, ṣàmójúkúrò ní àmójúkúrò tó rẹwà. info
التفاسير:

external-link copy
86 : 15

إِنَّ رَبَّكَ هُوَ ٱلۡخَلَّٰقُ ٱلۡعَلِيمُ

Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ẹlẹ́dàá, Onímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
87 : 15

وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَٰكَ سَبۡعٗا مِّنَ ٱلۡمَثَانِي وَٱلۡقُرۡءَانَ ٱلۡعَظِيمَ

Dájúdájú A fún ọ ní Sab‘u Mọthānī (ìyẹn, sūrah al-Fātihah) àti al-Ƙur’ān Ńlá. info
التفاسير:

external-link copy
88 : 15

لَا تَمُدَّنَّ عَيۡنَيۡكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعۡنَا بِهِۦٓ أَزۡوَٰجٗا مِّنۡهُمۡ وَلَا تَحۡزَنۡ عَلَيۡهِمۡ وَٱخۡفِضۡ جَنَاحَكَ لِلۡمُؤۡمِنِينَ

Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣíjú rẹ méjèèjì wo ohun tí A fi ṣe ìgbádún ayé fún oríṣiríṣi àwọn kan nínú àwọn aláìgbàgbọ́. Má ṣe banújẹ́ nítorí wọn. Kí o sì rẹ apá rẹ nílẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
89 : 15

وَقُلۡ إِنِّيٓ أَنَا ٱلنَّذِيرُ ٱلۡمُبِينُ

Kí o sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.” info
التفاسير:

external-link copy
90 : 15

كَمَآ أَنزَلۡنَا عَلَى ٱلۡمُقۡتَسِمِينَ

Gẹ́gẹ́ bí A ṣe sọ (ìyà) kalẹ̀ fún àwọn tó ń pín òdodo mọ́ irọ́; info
التفاسير: