ការបកប្រែអត្ថន័យគួរអាន - ការបកប្រែជាភាសាយ៉ូរូវ - អាពូ រ៉ហុីម៉ះ មុីកាអុីល

លេខ​ទំព័រ:close

external-link copy
16 : 15

وَلَقَدۡ جَعَلۡنَا فِي ٱلسَّمَآءِ بُرُوجٗا وَزَيَّنَّٰهَا لِلنَّٰظِرِينَ

A kúkú fi àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀ (ayé). A ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 15

وَحَفِظۡنَٰهَا مِن كُلِّ شَيۡطَٰنٖ رَّجِيمٍ

A sì ṣọ́ ọ kúrò lọ́dọ̀ gbogbo ṣaetọ̄n, ẹni ẹ̀kọ̀.[1] info

1. “A ṣe é ní ọ̀ṣọ́” àti “A sì ṣọ́ ọ”, kí ni A ṣe ní ọ̀ṣọ́? Kí ni A ṣọ́? Àwọn tafsīr kan sọ pé, sánmọ̀ ni. Àwọn kan sọ pé, àwọn ìràwọ̀ ni.

التفاسير:

external-link copy
18 : 15

إِلَّا مَنِ ٱسۡتَرَقَ ٱلسَّمۡعَ فَأَتۡبَعَهُۥ شِهَابٞ مُّبِينٞ

Àfi (ṣaetọ̄n) tí ó bá jí ọ̀rọ̀ gbọ́. Nígbà náà sì ni ògúnná pọ́nńbélé yó tẹ̀lé e láti ẹ̀yìn. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 15

وَٱلۡأَرۡضَ مَدَدۡنَٰهَا وَأَلۡقَيۡنَا فِيهَا رَوَٰسِيَ وَأَنۢبَتۡنَا فِيهَا مِن كُلِّ شَيۡءٖ مَّوۡزُونٖ

Ilẹ̀, A tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ. A sì ju àwọn àpáta tó dúró gbagidi sínú rẹ̀. A sì mú gbogbo n̄ǹkan tí ó ní òdíwọ̀n hù jáde láti inú rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 15

وَجَعَلۡنَا لَكُمۡ فِيهَا مَعَٰيِشَ وَمَن لَّسۡتُمۡ لَهُۥ بِرَٰزِقِينَ

A ṣe ọ̀nà ìjẹ-ìmu sínú (ilé ayé) fun ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ̀yin kò lè pèsè fún. info
التفاسير:

external-link copy
21 : 15

وَإِن مِّن شَيۡءٍ إِلَّا عِندَنَا خَزَآئِنُهُۥ وَمَا نُنَزِّلُهُۥٓ إِلَّا بِقَدَرٖ مَّعۡلُومٖ

Kò sì sí kiní kan àfi kí ilé-ọrọ̀ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ Wa. Àwa kò sì níí sọ̀ ọ́ kalẹ̀ àfi pẹ̀lú òdíwọ̀n tí A ti mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 15

وَأَرۡسَلۡنَا ٱلرِّيَٰحَ لَوَٰقِحَ فَأَنزَلۡنَا مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَسۡقَيۡنَٰكُمُوهُ وَمَآ أَنتُمۡ لَهُۥ بِخَٰزِنِينَ

Àti pé A rán àwọn atẹ́gùn láti kó àwọn ẹ̀ṣújò jọ. A sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. Nítorí náà, A fún yín mu. Ẹ̀yin sì kọ́ ni ẹ kó omi òjò jọ (sójú sánmọ̀). info
التفاسير:

external-link copy
23 : 15

وَإِنَّا لَنَحۡنُ نُحۡيِۦ وَنُمِيتُ وَنَحۡنُ ٱلۡوَٰرِثُونَ

Dájúdájú Àwa, Àwa ń sọ (ẹ̀dá) di alààyè. A sì ń sọ ọ́ di òkú. Àwa sì ni A óò jogún (ẹ̀dá). info
التفاسير:

external-link copy
24 : 15

وَلَقَدۡ عَلِمۡنَا ٱلۡمُسۡتَقۡدِمِينَ مِنكُمۡ وَلَقَدۡ عَلِمۡنَا ٱلۡمُسۡتَـٔۡخِرِينَ

Àti pé dájúdájú A mọ àwọn olùgbawájú nínú yín. Dájúdájú A sì mọ àwọn olùgbẹ̀yìn. info
التفاسير:

external-link copy
25 : 15

وَإِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَحۡشُرُهُمۡۚ إِنَّهُۥ حَكِيمٌ عَلِيمٞ

Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó máa kó wọn jọ. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
26 : 15

وَلَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ مِن صَلۡصَٰلٖ مِّنۡ حَمَإٖ مَّسۡنُونٖ

Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà sí dúdú. info
التفاسير:

external-link copy
27 : 15

وَٱلۡجَآنَّ خَلَقۡنَٰهُ مِن قَبۡلُ مِن نَّارِ ٱلسَّمُومِ

Àti pé àlùjànnú, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ṣíwájú (ènìyàn) láti ara iná alátẹ́gùn gbígbóná tí kò ní èéfín. info
التفاسير:

external-link copy
28 : 15

وَإِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَٰٓئِكَةِ إِنِّي خَٰلِقُۢ بَشَرٗا مِّن صَلۡصَٰلٖ مِّنۡ حَمَإٖ مَّسۡنُونٖ

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò ṣe ẹ̀dá abara kan láti ara amọ̀ tó ń dún koko, tó ti pàwọ̀dà sí dúdú. info
التفاسير:

external-link copy
29 : 15

فَإِذَا سَوَّيۡتُهُۥ وَنَفَخۡتُ فِيهِ مِن رُّوحِي فَقَعُواْ لَهُۥ سَٰجِدِينَ

Nígbà tí Mo bá ṣe é tó gún régétán, tí Mo fẹ́ ẹ̀mí sí i (lára) nínú ẹ̀mí Mi (tí Mo dá), nígbà náà ẹ dojú bolẹ̀ fún un ní olùforíkanlẹ̀-kíni.”[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah; 2:34.

التفاسير:

external-link copy
30 : 15

فَسَجَدَ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ كُلُّهُمۡ أَجۡمَعُونَ

Nítorí náà, àwọn mọlāika, gbogbo wọn pátápátá sì forí kanlẹ̀ kí i. info
التفاسير:

external-link copy
31 : 15

إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰٓ أَن يَكُونَ مَعَ ٱلسَّٰجِدِينَ

Àyàfi ’Iblīs. Ó kọ̀ láti wà nínú àwọn olùforíkanlẹ̀-kíni náà. info
التفاسير: