Traduzione dei Significati del Sacro Corano - Traduzione in yoruba - Abu Rahima Mikail

Ash-Shar'h

external-link copy
1 : 94

أَلَمۡ نَشۡرَحۡ لَكَ صَدۡرَكَ

Ṣé A kò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí? info
التفاسير:

external-link copy
2 : 94

وَوَضَعۡنَا عَنكَ وِزۡرَكَ

A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ, info
التفاسير:

external-link copy
3 : 94

ٱلَّذِيٓ أَنقَضَ ظَهۡرَكَ

èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn.[1] info

1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò ṣẹbọ rí ṣíwájú kí ó tó di Òjíṣẹ́ Allāhu, ọ̀kan nínú ohun tí ó máa ń kọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lóminú, tí ó sì máa ń bà á nínú jẹ́ ni àìdá ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀ àti àìní ìlànà ìjọ́sìn kan lọ́wọ́ ṣíwájú ogójì ọdún tí ó kọ́kọ́ lò.

التفاسير:

external-link copy
4 : 94

وَرَفَعۡنَا لَكَ ذِكۡرَكَ

A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 94

فَإِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرًا

Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 94

إِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرٗا

Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 94

فَإِذَا فَرَغۡتَ فَٱنصَبۡ

Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ohun tí ó jẹmọ́ táyé), gbìyànjú (dáadáa lórí ìjọ́sìn). info
التفاسير:

external-link copy
8 : 94

وَإِلَىٰ رَبِّكَ فَٱرۡغَب

Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí. info
التفاسير: