1. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - kò ṣẹbọ rí ṣíwájú kí ó tó di Òjíṣẹ́ Allāhu, ọ̀kan nínú ohun tí ó máa ń kọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lóminú, tí ó sì máa ń bà á nínú jẹ́ ni àìdá ìgbàgbọ́ òdodo mọ̀ àti àìní ìlànà ìjọ́sìn kan lọ́wọ́ ṣíwájú ogójì ọdún tí ó kọ́kọ́ lò.