Fassarar Ma'anonin Alqura'ni - Fassarar Yarabanci - Abu Ruhaimah Mika'il

Al-Mahaarij

external-link copy
1 : 70

سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٖ وَاقِعٖ

Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀ info
التفاسير:

external-link copy
2 : 70

لِّلۡكَٰفِرِينَ لَيۡسَ لَهُۥ دَافِعٞ

sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́ info
التفاسير:

external-link copy
3 : 70

مِّنَ ٱللَّهِ ذِي ٱلۡمَعَارِجِ

lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 70

تَعۡرُجُ ٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٖ كَانَ مِقۡدَارُهُۥ خَمۡسِينَ أَلۡفَ سَنَةٖ

Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).[1] info

1. Ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta ọdún (50,000). Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Hajj; 22:47.

التفاسير:

external-link copy
5 : 70

فَٱصۡبِرۡ صَبۡرٗا جَمِيلًا

Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 70

إِنَّهُمۡ يَرَوۡنَهُۥ بَعِيدٗا

Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 70

وَنَرَىٰهُ قَرِيبٗا

A sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 70

يَوۡمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلۡمُهۡلِ

(Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná, info
التفاسير:

external-link copy
9 : 70

وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ

àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun, info
التفاسير:

external-link copy
10 : 70

وَلَا يَسۡـَٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمٗا

ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀). info
التفاسير: