1. Ìyẹn ni pé, má fi àwọn kèfèrí borí wa, kí ayé má fi lérò pé wọ́n wà lórí òdodo ni wọ́n fi borí wa.
1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mọ̄’idah; 5:5. 2. Ìyẹn ni pé, mùsùlùmí lọ́kùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ẹ̀sìn ’Islām kò gbọ́dọ̀ tìtorí owó-orí ìyàwó rẹ láti má lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní àsìkò náà, tí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá kùnà láti gba ’Islām.