Firo maanaaji al-quraan tedduɗo oo - Eggo maanaaji Kur'aana e haala Yoruba - Ceerno Abu Rahima Mika'il

Tonngoode hello ngoo:close

external-link copy
107 : 9

وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مَسۡجِدٗا ضِرَارٗا وَكُفۡرٗا وَتَفۡرِيقَۢا بَيۡنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَإِرۡصَادٗا لِّمَنۡ حَارَبَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ مِن قَبۡلُۚ وَلَيَحۡلِفُنَّ إِنۡ أَرَدۡنَآ إِلَّا ٱلۡحُسۡنَىٰۖ وَٱللَّهُ يَشۡهَدُ إِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ

Àwọn tó kọ́ mọ́sálásí láti fi dá ìnira àti àìgbàgbọ́ sílẹ̀ àti láti fi ṣe òpínyà láààrin àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti láti fi ṣe ibùlúgọ fún àwọn tó gbógun ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ní ìṣáájú - dájúdájú wọ́n ń búra pé “A ò gbèrò kiní kan bí kò ṣe ohun rere.” - Allāhu sì ń jẹ́rìí pé dájúdájú òpùrọ́ ni wọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
108 : 9

لَا تَقُمۡ فِيهِ أَبَدٗاۚ لَّمَسۡجِدٌ أُسِّسَ عَلَى ٱلتَّقۡوَىٰ مِنۡ أَوَّلِ يَوۡمٍ أَحَقُّ أَن تَقُومَ فِيهِۚ فِيهِ رِجَالٞ يُحِبُّونَ أَن يَتَطَهَّرُواْۚ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلۡمُطَّهِّرِينَ

Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé.[1] Dájúdájú mọ́sálásí tí wọ́n bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu láti ọjọ́ àkọ́kọ́ lo lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o dúró (kírun) nínú rẹ̀. Àwọn ènìyàn tó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣe ìmọ́ra wà nínú rẹ̀. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣèmọ́ra. info

1. Kíyè sí i! Gbólóhùn yìí “Má ṣe dúró (kírun) nínú rẹ̀ láéláé.” àti āyah 107 ló ń ṣe é ní èèwọ̀ fún àwa mùsùlùmí onisunnah láti kírun nínú àwọn mọ́sálásí àwọn mùsùlùmí onibidiah pẹ̀lú májẹ̀mu pé tí ó bá jẹ́ pé wọ́n fi mọ́sálásí náà sọrí bid‘ah wọn. Irú àwọn mọ́sálásí tí èyí kàn ni mọ́sálásí Ahmadiyyah àti Zāwiyah àwọn oníwírìdí Tijāniyah, Ƙọ̄diriyyah àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

التفاسير:

external-link copy
109 : 9

أَفَمَنۡ أَسَّسَ بُنۡيَٰنَهُۥ عَلَىٰ تَقۡوَىٰ مِنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنٍ خَيۡرٌ أَم مَّنۡ أَسَّسَ بُنۡيَٰنَهُۥ عَلَىٰ شَفَا جُرُفٍ هَارٖ فَٱنۡهَارَ بِهِۦ فِي نَارِ جَهَنَّمَۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّٰلِمِينَ

Ǹjẹ́ ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ lórí ìbẹ̀rù Allāhu àti ìyọ́nú (Rẹ̀) ló lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilé mímọ tirẹ̀ lélẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ kan létí ọ̀gbun tó máa yẹ̀ lulẹ̀, tí ó sì máa yẹ̀ ẹ́ lẹ́sẹ̀ sínú iná Jahanamọ? Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí. info
التفاسير:

external-link copy
110 : 9

لَا يَزَالُ بُنۡيَٰنُهُمُ ٱلَّذِي بَنَوۡاْ رِيبَةٗ فِي قُلُوبِهِمۡ إِلَّآ أَن تَقَطَّعَ قُلُوبُهُمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ

Ilé wọn tí wọ́n mọ kalẹ̀ kò níí yé kó iyèméjì sínú ọkàn wọn títí ọkàn wọn yóò fi já kélekèle. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
111 : 9

۞ إِنَّ ٱللَّهَ ٱشۡتَرَىٰ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ أَنفُسَهُمۡ وَأَمۡوَٰلَهُم بِأَنَّ لَهُمُ ٱلۡجَنَّةَۚ يُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ فَيَقۡتُلُونَ وَيُقۡتَلُونَۖ وَعۡدًا عَلَيۡهِ حَقّٗا فِي ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَٱلۡإِنجِيلِ وَٱلۡقُرۡءَانِۚ وَمَنۡ أَوۡفَىٰ بِعَهۡدِهِۦ مِنَ ٱللَّهِۚ فَٱسۡتَبۡشِرُواْ بِبَيۡعِكُمُ ٱلَّذِي بَايَعۡتُم بِهِۦۚ وَذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ

Dájúdájú Allāhu ra ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti dúkìá wọn nítorí pé dájúdájú tiwọn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra. Wọ́n ń jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu; wọ́n ń pa ọ̀tá ẹ̀sìn, wọ́n sì ń pa àwọn náà. (Ó jẹ́) àdéhùn òdodo lọ́dọ̀ Allāhu nínú at-Taorāh, al-’Injīl àti al-Ƙur’ān. Ta sì ni ó lè mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ ju Allāhu? Nítorí náà, ẹ dunnú sí òkòwò yín tí ẹ (fi ẹ̀mí àti dúkìá yin) ṣe. Ìyẹn, òhun sì ni èrèǹjẹ ńlá. info
التفاسير: