1. Ìyà ẹ̀ẹ̀ mejì dúró fún ìyà tayé àti ìya tinú sàréè.
1. Àwọn ikọ̀ méjì ni āyah yìí ń sọ nípa wọn. Ikọ̀ kìíní ni àwọn tó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá wọn - ní ìbámu sí āyah 102 tó ṣíwájú. Ikọ̀ kejì ni àwọn tó ń yọ zakāh. Zakāh yíyọ sì jẹ́ àfọ̀mọ́ dúkìá fún ẹni tí ó yọ ọ́.
1. Āyah yìí jọ āyah 94 nínú sūrah yìí. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Āli ‘Imrọ̄n; 3:101 àti sūrah an-Nisā’; 4:64.
1. Ìyẹn, àwọn tó ṣàì lọ sógun, àmọ́ tí wọn kò mú àwáwí irọ́ wá. 2. Àṣẹ náà dé nínú āyah 118 níwájú.