1. Wọ́n bẹ̀rù láti fi àìgbàgbọ́ wọn hàn síta, wọ́n yáa ń fi ’Islām wọn ṣe bojúbojú.
1. N̄ǹkan tí āyah yìí ń sọ ni pé, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́tọ̀ọ́ sí pípín àwọn ọrẹ tí Allāhu pín kàn án nínú àwọn oore ayé àrígbámú yálà nípasẹ̀ ọrọ̀ ogun, zakāh gbígbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
1. “Faƙīr” ni aláìní, tálíkà, olòṣì. Ìyẹn ni ẹni tí ó fẹ́ ṣiṣẹ́, àmọ́ tí kò rí iṣẹ́ kan kan ṣe, yálà lábẹ́ ènìyàn tàbí iṣẹ́ àdáni. Kò sì ní ọ̀nà kan kan tí ó lè gbà rí owó. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tara tirẹ̀. “Miskīn” ni mẹ̀kúnnù. Ìyẹn ni ẹni tí ó ń rí iṣẹ́ kan ṣe, àmọ́ tí owó tó ń rí lórí iṣẹ́ náà kò ká àpapọ̀ bùkátà ìjẹ-ìmu rẹ̀, owó ilé gbígbé rẹ̀ àti gbígbọ́ bùkátà lórí ará ilé rẹ̀. Kí wọ́n fún un nínú zakah kí ó fi yanjú bùkátà ọrùn rẹ̀.