Übersetzung der Bedeutungen von dem heiligen Quran - Die Übersetzung in Yoruba - Abu Rahimah Mikail

Nummer der Seite:close

external-link copy
176 : 4

يَسۡتَفۡتُونَكَ قُلِ ٱللَّهُ يُفۡتِيكُمۡ فِي ٱلۡكَلَٰلَةِۚ إِنِ ٱمۡرُؤٌاْ هَلَكَ لَيۡسَ لَهُۥ وَلَدٞ وَلَهُۥٓ أُخۡتٞ فَلَهَا نِصۡفُ مَا تَرَكَۚ وَهُوَ يَرِثُهَآ إِن لَّمۡ يَكُن لَّهَا وَلَدٞۚ فَإِن كَانَتَا ٱثۡنَتَيۡنِ فَلَهُمَا ٱلثُّلُثَانِ مِمَّا تَرَكَۚ وَإِن كَانُوٓاْ إِخۡوَةٗ رِّجَالٗا وَنِسَآءٗ فَلِلذَّكَرِ مِثۡلُ حَظِّ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۗ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ أَن تَضِلُّواْۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمُۢ

Wọ́n ń bi ọ́ léèrè ìbéèrè, sọ pé: “Allāhu ń fún yín ní ìdájọ́ nípa ẹni tí kò ní òbí, kò sì ní ọmọ. Tí ènìyàn kan bá kú, tí kò ní ọmọ láyé, tí ó sì ní arábìnrin kan, ìdajì ni tirẹ̀ nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. (Arákùnrin) l’ó máa jẹ gbogbo ogún arábìnrin rẹ̀, tí kò bá ní ọmọ láyé. Tí arábìnrin bá sì jẹ́ méjì, ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta ni tiwọn nínú ohun tí ó fi sílẹ̀. Tí wọ́n bá sì jẹ́ ará (púpọ̀) lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ti ọkùnrin kan ni ìpín obìnrin méjì. Allāhu ń ṣe àlàyé fún yín kí ẹ má baà ṣìnà. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan. info
التفاسير: