Übersetzung der Bedeutungen von dem heiligen Quran - Die Übersetzung in Yoruba - Abu Rahimah Mikail

Nummer der Seite:close

external-link copy
45 : 4

وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِأَعۡدَآئِكُمۡۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَلِيّٗا وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ نَصِيرٗا

Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn ọ̀tá yín. Allāhu tó ní Aláàbò. Allāhu sì tó ní Alárànṣe. info
التفاسير:

external-link copy
46 : 4

مِّنَ ٱلَّذِينَ هَادُواْ يُحَرِّفُونَ ٱلۡكَلِمَ عَن مَّوَاضِعِهِۦ وَيَقُولُونَ سَمِعۡنَا وَعَصَيۡنَا وَٱسۡمَعۡ غَيۡرَ مُسۡمَعٖ وَرَٰعِنَا لَيَّۢا بِأَلۡسِنَتِهِمۡ وَطَعۡنٗا فِي ٱلدِّينِۚ وَلَوۡ أَنَّهُمۡ قَالُواْ سَمِعۡنَا وَأَطَعۡنَا وَٱسۡمَعۡ وَٱنظُرۡنَا لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۡ وَأَقۡوَمَ وَلَٰكِن لَّعَنَهُمُ ٱللَّهُ بِكُفۡرِهِمۡ فَلَا يُؤۡمِنُونَ إِلَّا قَلِيلٗا

Ó ń bẹ nínú àwọn yẹhudi, àwọn tó ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “A gbọ́, a sì yapa. Gbọ́rọ̀ bí ẹni tí etí rẹ̀ ti di, òmùgọ̀ wa.”[1] Wọ́n ń fi ahọ́n wọn yí ọ̀rọ̀ sódì àti pé wọ́n ń bu ẹnu-àtẹ́ lu ẹ̀sìn. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n sọ pé: “A gbọ́, a sì tẹ̀lé e. Gbọ́, kí o sì kíyè sí wa”, ìbá dára fún wọn, ìbá sì tọ̀nà jùlọ. Ṣùgbọ́n Allāhu fi wọ́n gégùn-ún nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi díẹ̀ (nínú wọn). info

1. Ẹ wọ ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Baƙọrah 2:104.

التفاسير:

external-link copy
47 : 4

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ ءَامِنُواْ بِمَا نَزَّلۡنَا مُصَدِّقٗا لِّمَا مَعَكُم مِّن قَبۡلِ أَن نَّطۡمِسَ وُجُوهٗا فَنَرُدَّهَا عَلَىٰٓ أَدۡبَارِهَآ أَوۡ نَلۡعَنَهُمۡ كَمَا لَعَنَّآ أَصۡحَٰبَ ٱلسَّبۡتِۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ مَفۡعُولًا

Ẹ̀yin tí A fún ní tírà, ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín, ṣíwájú kí Á tó fọ́ àwọn ojú kan, A sì máa dá a padà sí (ìpàkọ́) lẹ́yìn wọn, tàbí kí Á ṣẹ́bi lé wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ́bi lé ìjọ Sabt. Àti pé àṣẹ Allāhu máa ṣẹ. info
التفاسير:

external-link copy
48 : 4

إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَغۡفِرُ أَن يُشۡرَكَ بِهِۦ وَيَغۡفِرُ مَا دُونَ ذَٰلِكَ لِمَن يَشَآءُۚ وَمَن يُشۡرِكۡ بِٱللَّهِ فَقَدِ ٱفۡتَرَىٰٓ إِثۡمًا عَظِيمًا

Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I.[1] Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ẹni tí ó bá ń ṣẹbọ sí Allāhu, dájúdájú ó ti dá àdápa irọ́ (tí ó jẹ́) ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. info

1. Ìyẹn ni ìdájọ́ ẹni tí ó kú sórí “aṣ-ṣirk” ẹbọ.

التفاسير:

external-link copy
49 : 4

أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ يُزَكُّونَ أَنفُسَهُمۚ بَلِ ٱللَّهُ يُزَكِّي مَن يَشَآءُ وَلَا يُظۡلَمُونَ فَتِيلًا

Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tó ń ṣàfọ̀mọ́ ara wọn ni? Kò sì rí bẹ́ẹ̀, Allāhu l’Ó ń ṣàfọ̀mọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́. Wọn kò sì níí fi (ohun tó tó) ìbójú kóró èso dàbínù ṣàbòsí sí wọn.[1] info

1. Ìyẹn ni pé, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní ẹ̀san ọ̀run, kò níí dín rárá.

التفاسير:

external-link copy
50 : 4

ٱنظُرۡ كَيۡفَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَۖ وَكَفَىٰ بِهِۦٓ إِثۡمٗا مُّبِينًا

Wo bí wọ́n ṣe ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Ó sì tó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ́nńbélé. info
التفاسير:

external-link copy
51 : 4

أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ أُوتُواْ نَصِيبٗا مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡجِبۡتِ وَٱلطَّٰغُوتِ وَيَقُولُونَ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ هَٰٓؤُلَآءِ أَهۡدَىٰ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ سَبِيلًا

Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A fún ní ìpín kan nínú tírà, tí wọ́n ń gbàgbọ́ nínú idán àti òrìṣà, wọ́n sì ń wí fún àwọn aláìgbàgbọ́ pé: “Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) wọ̀nyí mọ̀nà ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” info
التفاسير: