Qurani Kərimin mənaca tərcüməsi - Yorba dilinə tərcümə- Əbu Rəhimə Mikayıl.

Al-Maidah

external-link copy
1 : 5

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَوۡفُواْ بِٱلۡعُقُودِۚ أُحِلَّتۡ لَكُم بَهِيمَةُ ٱلۡأَنۡعَٰمِ إِلَّا مَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡكُمۡ غَيۡرَ مُحِلِّي ٱلصَّيۡدِ وَأَنتُمۡ حُرُمٌۗ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ مَا يُرِيدُ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ mú àwọn àdéhùn ṣẹ. Wọ́n ṣe àwọn ẹran-ọ̀sìn[1] ní ẹ̀tọ́ fún yín àfi èyí tí wọ́n bá ń kà fún yín (ní èèwọ̀), ẹ má ṣe sọ ìdọdẹ ẹranko di ẹ̀tọ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ húrùmí. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ìdájọ́ ohun tí Ó bá fẹ́. info

1. Àwọn ẹran-ọ̀sìn náà ni ràkúnmí, màálù, àgùtàn àti ewúrẹ́.

التفاسير: