Qurani Kərimin mənaca tərcüməsi - Yorba dilinə tərcümə- Əbu Rəhimə Mikayıl.

external-link copy
6 : 4

وَٱبۡتَلُواْ ٱلۡيَتَٰمَىٰ حَتَّىٰٓ إِذَا بَلَغُواْ ٱلنِّكَاحَ فَإِنۡ ءَانَسۡتُم مِّنۡهُمۡ رُشۡدٗا فَٱدۡفَعُوٓاْ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡۖ وَلَا تَأۡكُلُوهَآ إِسۡرَافٗا وَبِدَارًا أَن يَكۡبَرُواْۚ وَمَن كَانَ غَنِيّٗا فَلۡيَسۡتَعۡفِفۡۖ وَمَن كَانَ فَقِيرٗا فَلۡيَأۡكُلۡ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ فَإِذَا دَفَعۡتُمۡ إِلَيۡهِمۡ أَمۡوَٰلَهُمۡ فَأَشۡهِدُواْ عَلَيۡهِمۡۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبٗا

Ẹ dán àwọn ọmọ òrukàn wò[1] títí wọn yóò fi dàgbà wọ ẹni tí ò lè ṣe ìgbéyàwó.² Tí ẹ bá sì ti rí òye lára wọn, kí ẹ dá dúkìá wọn padà fún wọn. Ẹ ò gbọdọ̀ jẹ dúkìá wọn ní ìjẹ àpà àti ìjẹkújẹ kí wọ́n tó dàgbà. Ẹni tí ó bá jẹ́ ọlọ́rọ̀, kí ó mójú kúrò (níbẹ̀). Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìní, kí ó jẹ nínú rẹ̀ ní ọ̀nà tó dára. Nítorí náà, tí ẹ bá fẹ́ dá dúkìá wọn padà fún wọn, ẹ pe àwọn ẹlẹ́rìí sí wọn. Allāhu sì tó ní Olùṣírò. info

1. Ìyẹn ni pé, ẹ kọ́kọ́ fi díẹ̀ tó kéré gan-an lé e lọ́wọ́ nínú ogún rẹ̀ tó jẹ́ ohun àmúṣọrọ̀, kí ẹ wo bí ó ṣe máa ṣe àmójútó rẹ̀. 2. “eni tí ó lè ṣe ìgbéyàwó” ni ẹni tí ó ti di ọmọkùnrin tàbí ẹni tí ó ti di ọmọbìnrin ẹni tí “ó ti bàlágà”.

التفاسير: