Qurani Kərimin mənaca tərcüməsi - Yorba dilinə tərcümə- Əbu Rəhimə Mikayıl.

Səhifənin rəqəmi:close

external-link copy
18 : 17

مَّن كَانَ يُرِيدُ ٱلۡعَاجِلَةَ عَجَّلۡنَا لَهُۥ فِيهَا مَا نَشَآءُ لِمَن نُّرِيدُ ثُمَّ جَعَلۡنَا لَهُۥ جَهَنَّمَ يَصۡلَىٰهَا مَذۡمُومٗا مَّدۡحُورٗا

Ẹni tí ó bá ń gbèrò (oore) ayé yìí (nìkan), A máa taari ohun tí A bá fẹ́ sí i nínú rẹ̀ ní kíákíá fún ẹni tí A bá fẹ́. Lẹ́yìn náà, A máa ṣe iná Jahanamọ fún un; ó máa wọ inú rẹ̀ ní ẹni èébú, ẹni ẹ̀kọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
19 : 17

وَمَنۡ أَرَادَ ٱلۡأٓخِرَةَ وَسَعَىٰ لَهَا سَعۡيَهَا وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَأُوْلَٰٓئِكَ كَانَ سَعۡيُهُم مَّشۡكُورٗا

Ẹni tí ó bá sì gbèrò (oore) ọ̀run, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rẹ̀ fún ọ̀run náà, ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, àwọn wọ̀nyẹn, wọ́n máa fi ẹ̀san rere àdìpèlé dúpẹ́ iṣẹ́ wọn fún wọn. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 17

كُلّٗا نُّمِدُّ هَٰٓؤُلَآءِ وَهَٰٓؤُلَآءِ مِنۡ عَطَآءِ رَبِّكَۚ وَمَا كَانَ عَطَآءُ رَبِّكَ مَحۡظُورًا

Àwọn wọ̀nyí (tó ń gbèrò oore ayé) àti àwọn wọ̀nyí (tó ń gbèrò oore ọ̀run), gbogbo wọn ni À ń ṣe oore ayé fún láti inú ọrẹ Olúwa rẹ. Wọn kò níí dí ọrẹ Olúwa rẹ lọ́wọ́ (fún ìkíní kejì nílé ayé). info
التفاسير:

external-link copy
21 : 17

ٱنظُرۡ كَيۡفَ فَضَّلۡنَا بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۚ وَلَلۡأٓخِرَةُ أَكۡبَرُ دَرَجَٰتٖ وَأَكۡبَرُ تَفۡضِيلٗا

Wo bí A ṣe fún apá kan wọn lóore àjùlọ lórí apá kan (nílé ayé). Dájúdájú tọ̀run tún tóbi jùlọ ní ipò, ó sì tóbi jùlọ lóore àjùlọ. info
التفاسير:

external-link copy
22 : 17

لَّا تَجۡعَلۡ مَعَ ٱللَّهِ إِلَٰهًا ءَاخَرَ فَتَقۡعُدَ مَذۡمُومٗا مَّخۡذُولٗا

Má ṣe mú ọlọ́hun mìíràn mọ́ Allāhu nítorí kí o má baà jókòó (sínú Iná) ní ẹni àbùkù, ẹni ẹ̀kọ̀ (tí wọ́n máa dá ìṣòro rẹ̀ dá). info
التفاسير:

external-link copy
23 : 17

۞ وَقَضَىٰ رَبُّكَ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّآ إِيَّاهُ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنًاۚ إِمَّا يَبۡلُغَنَّ عِندَكَ ٱلۡكِبَرَ أَحَدُهُمَآ أَوۡ كِلَاهُمَا فَلَا تَقُل لَّهُمَآ أُفّٖ وَلَا تَنۡهَرۡهُمَا وَقُل لَّهُمَا قَوۡلٗا كَرِيمٗا

Olúwa rẹ pàṣẹ pé: “Ẹ má ṣe jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Òun. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì tàbí ìkíní kejì wọn bá dàgbà sí ọ lọ́dọ̀, má ṣe ṣíọ̀ sí wọn, má ṣe jágbe mọ́ wọn. Máa bá àwọn méjèèjì sọ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé. info
التفاسير:

external-link copy
24 : 17

وَٱخۡفِضۡ لَهُمَا جَنَاحَ ٱلذُّلِّ مِنَ ٱلرَّحۡمَةِ وَقُل رَّبِّ ٱرۡحَمۡهُمَا كَمَا رَبَّيَانِي صَغِيرٗا

Rẹ apá rẹ nílẹ̀ dáadáa (bọ̀wọ̀) fún àwọn méjèèjì nípa ṣíṣe àánú wọn. Kí o sì sọ pé: “Olúwa Ẹlẹ́dàá mi, kẹ́ àwọn méjèèjì nítorí pé, àwọn méjèèjì náà tọ́ mi ní kékeré.” info
التفاسير:

external-link copy
25 : 17

رَّبُّكُمۡ أَعۡلَمُ بِمَا فِي نُفُوسِكُمۡۚ إِن تَكُونُواْ صَٰلِحِينَ فَإِنَّهُۥ كَانَ لِلۡأَوَّٰبِينَ غَفُورٗا

Olúwa yín nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, tí ẹ bá jẹ́ ẹni rere. Dájúdájú Ó ń jẹ́ Aláforíjìn fún àwọn olùronúpìwàdà. info
التفاسير:

external-link copy
26 : 17

وَءَاتِ ذَا ٱلۡقُرۡبَىٰ حَقَّهُۥ وَٱلۡمِسۡكِينَ وَٱبۡنَ ٱلسَّبِيلِ وَلَا تُبَذِّرۡ تَبۡذِيرًا

Fún ẹbí ní ẹ̀tọ́ rẹ̀. (Fún) mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá ní n̄ǹkan). Kí o sì má ṣe ná dúkìá yín ní ìná-àpà. info
التفاسير:

external-link copy
27 : 17

إِنَّ ٱلۡمُبَذِّرِينَ كَانُوٓاْ إِخۡوَٰنَ ٱلشَّيَٰطِينِۖ وَكَانَ ٱلشَّيۡطَٰنُ لِرَبِّهِۦ كَفُورٗا

Dájúdájú àwọn àpà, wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá àwọn ṣaetọ̄n. Aláìmoore sì ni aṣ-Ṣaetọ̄n jẹ́ sí Olúwa rẹ̀. info
التفاسير: