1. Ọgọ́rùn-ún kòbókò àti ẹ̀wọ̀n ọdún kan tàbí ọgọ́rùn-ún kòbókò àti lílé kúrò nínú ìlú fún ọdún kan ni ìjìyà fún onísìná tí kò ì ṣe ‘akdu-nnikāh pẹ̀lú ẹnikẹ́ni rí. Àmọ́ lílẹ̀ lókòpa ni ìjìyà fún onísìná tí ó ti ṣe ‘akdu-nnikāh rí.
1. Àwọn onímọ̀ pín sí mẹ́ta lórí ìtúmọ̀ āyah yìí nítorí pé, ìtúmọ̀ mẹ́ta tí ó ń padà síbi n̄ǹkan ẹyọ kan ni kalmọh “nikāh” ń túmọ̀ sí nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni fífẹ́ (ṣíṣe ìgbéyàwó), títi kálámù bọ inú ìgò tàdáà yálà ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tàbí ní ọ̀nà àìtọ́ àti ṣíṣe sìná (àgbèrè). 2. Nítorí náà, “ìyẹn” nínú gbólóhùn yìí “A sì ṣe ìyẹn ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” ń tọ́ka sí “zinā”. Ìyẹn ni pé, “A sì ṣe zinā ṣíṣe ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” Èyí sì ni ìtúmọ̀ rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ tí ó túmọ̀ “lā yankihu” sí “kò níí ṣe sìná”.
1. Ẹ̀sùn zinā lágbára púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tó jẹ́ pé kòbókò ọgọrin ni ìjìyà tí Allāhu gbékalẹ̀ lórí ẹni tí ó bá parọ́ zina mọ́ ẹlòmíìràn.
1. Tí abilékọ bá ní oyún tàbí bí ọmọ, àmọ́ tí ọkọ rẹ̀ sọ pé kì í ṣe tòun ni oyún náà tàbí ọmọ náà, tí ìyàwó sì takú pé ọkọ òun ló ni í, ìgbéyàwó náà máa túká pẹ̀lú ìṣẹ́bi láààrin tọkọ tìyàwo náà lórí ìlànà tó wà nínú āyah 6 sí āyah 9. Lẹ́yìn ìṣẹ́bi náà, ọmọ náà yóò máa bá ìyá rẹ̀ lọ. Ìkíní kejì kò sì lè di tọkọ tìyàwó mọ́.