1. Àwọn onímọ̀ pín sí mẹ́ta lórí ìtúmọ̀ āyah yìí nítorí pé, ìtúmọ̀ mẹ́ta tí ó ń padà síbi n̄ǹkan ẹyọ kan ni kalmọh “nikāh” ń túmọ̀ sí nínú al-Ƙur’ān, hadīth àti èdè Lárúbáwá. Àwọn ìtúmọ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni fífẹ́ (ṣíṣe ìgbéyàwó), títi kálámù bọ inú ìgò tàdáà yálà ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ tàbí ní ọ̀nà àìtọ́ àti ṣíṣe sìná (àgbèrè). 2. Nítorí náà, “ìyẹn” nínú gbólóhùn yìí “A sì ṣe ìyẹn ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” ń tọ́ka sí “zinā”. Ìyẹn ni pé, “A sì ṣe zinā ṣíṣe ní èèwọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.” Èyí sì ni ìtúmọ̀ rẹ̀ ní ọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ tí ó túmọ̀ “lā yankihu” sí “kò níí ṣe sìná”.