1. Kò sí ìtakora láààrin gbólóhùn yìí “Tí wọ́n bá jẹ́ aláìní, Allāhu yóò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.” àti gbólóhùn yìí. “Kí àwọn tí kò ní (ìkápá) ìgbéyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.” Gbólóhùn kìíní ń kìlọ̀ fún wa láti jìnnà sí fífí ọmọ fún olówó nìkan. Gbólóhùn kejì sì ń kìlọ̀ fún wa láti jìnnà sí fífi ìyàwó fún ẹni tí kò ní ọ̀nà kan kan láti máa fi bọ́ ìyàwó. 2. Awẹ́ gbólóhùn “tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.” kì í ṣe májẹ̀mu fún awẹ́ gbólóhùn tó ṣíwájú. Ìyẹn ni pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe lérò pé bí ẹrúbìnrin kò bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ rẹ̀, olówó rẹ̀ lè rán an lọ ṣe sìná wá. Rárá o. Àfijọ ọ̀rọ̀ yìí dà bí awẹ́ gbólóhùn “èyí tó ń bẹ nínú ilé yín…” - sūrah an-Nisā; 4:23 - . Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ āyah náà. 3. Ìyẹn fún ẹrúbìnrin tí olówó rẹ̀ jẹ nípá láti lọ ṣe sìná.
1. Ìyẹn ni pé, kò gba ìmọ́lẹ̀ ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn nìkan mọ bí kò ṣe pé, ó ń gba ìmọ́lẹ̀ sára ní gbogbo àyíká rẹ̀. 2. Ìyẹn ni pé, ó ń dá mú ìmọ́lẹ̀ tirẹ̀ wá. Bí wọ́n bá tún tan iná sí i lára, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tún máa lágbára sí i gan-an.
1. Ṣíṣe àgbéga mọ́sálásí kò tayọ kíkọ́ mọ́sálásì ní ilé gíga, ṣíṣe sunnah nínú rẹ̀, jíjìnnà sí fífi bidi‘ah lọ́lẹ̀ nínú rẹ̀ àti bíbu ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ fún un. 2. Ṣíṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́ nínú mọ́sálásí kò túmọ̀ sí ṣíṣe é ní àpapọ̀ pẹ̀lú ariwo bí tàwọn onisūfī.