ترجمة معاني القرآن الكريم - الترجمة اليورباوية - أبو رحيمة ميكائيل

سورة الأعلى - Al-A'laa

external-link copy
1 : 87

سَبِّحِ ٱسۡمَ رَبِّكَ ٱلۡأَعۡلَى

Ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 87

ٱلَّذِي خَلَقَ فَسَوَّىٰ

Ẹni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 87

وَٱلَّذِي قَدَّرَ فَهَدَىٰ

Ẹni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.[1] info

1. Ìkíní: ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām. Nítorí ìtọ́sọ́nà yìí gan-an ni Allāhu ṣe sọ àwọn Tírà Rẹ̀ kalẹ̀, tí Ó sì gbé àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ dìde sí wa. Ìkejì: ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí-ọkàn. Nípa èyí ni a fi mọ ohun rere àti ohun burúkú ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìkẹta: ìtọ́sọ́nà òye àtinúwá. Nípa èyí ni a ṣe ń ṣàmúlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ fún ìgbáyé-gbádùn.

التفاسير:

external-link copy
4 : 87

وَٱلَّذِيٓ أَخۡرَجَ ٱلۡمَرۡعَىٰ

Ẹni tí Ó mú koríko tútù hù jáde, info
التفاسير:

external-link copy
5 : 87

فَجَعَلَهُۥ غُثَآءً أَحۡوَىٰ

Ó sì sọ ọ́ di gbígbẹ tó dúdú. info
التفاسير:

external-link copy
6 : 87

سَنُقۡرِئُكَ فَلَا تَنسَىٰٓ

Àwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 87

إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّهُۥ يَعۡلَمُ ٱلۡجَهۡرَ وَمَا يَخۡفَىٰ

Àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́.[1] Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun tó pamọ́. info

1. Ìyẹn nípasẹ̀ fífí ìdájọ́ kan pa ìdájọ́ tó ṣíwájú rẹ̀ rẹ́. Ẹ wo sūrah al-Baƙọrah; 2:106.

التفاسير:

external-link copy
8 : 87

وَنُيَسِّرُكَ لِلۡيُسۡرَىٰ

Àwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 87

فَذَكِّرۡ إِن نَّفَعَتِ ٱلذِّكۡرَىٰ

Nítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.[1] info

1. Ìyẹn ni pé, wọ́n fẹ́ kí ṣíṣe ìrántí ọ̀rọ̀ Allāhu jìnnà sí àyè ìhunrírà (bí ilé ọtí), ilé eré àti ilé àwàdà.

التفاسير:

external-link copy
10 : 87

سَيَذَّكَّرُ مَن يَخۡشَىٰ

Ẹni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 87

وَيَتَجَنَّبُهَا ٱلۡأَشۡقَى

Olórí-burúkú sì máa takété sí i. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 87

ٱلَّذِي يَصۡلَى ٱلنَّارَ ٱلۡكُبۡرَىٰ

(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná tó tóbi. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 87

ثُمَّ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحۡيَىٰ

Lẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà). info
التفاسير:

external-link copy
14 : 87

قَدۡ أَفۡلَحَ مَن تَزَكَّىٰ

Dájúdájú ẹni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀sìn rẹ̀) ti jèrè.[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-Mu’minūn; 23:4.

التفاسير:

external-link copy
15 : 87

وَذَكَرَ ٱسۡمَ رَبِّهِۦ فَصَلَّىٰ

Ó sì rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun. info
التفاسير:

external-link copy
16 : 87

بَلۡ تُؤۡثِرُونَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا

Rárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 87

وَٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓ

Ọ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé. info
التفاسير:

external-link copy
18 : 87

إِنَّ هَٰذَا لَفِي ٱلصُّحُفِ ٱلۡأُولَىٰ

Dájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàǹdá àkọ́kọ́, info
التفاسير:

external-link copy
19 : 87

صُحُفِ إِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ

tákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā. info
التفاسير: