1. Ìkíní: ìtọ́sọ́nà ẹ̀sìn ’Islām. Nítorí ìtọ́sọ́nà yìí gan-an ni Allāhu ṣe sọ àwọn Tírà Rẹ̀ kalẹ̀, tí Ó sì gbé àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀ dìde sí wa. Ìkejì: ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí-ọkàn. Nípa èyí ni a fi mọ ohun rere àti ohun burúkú ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìkẹta: ìtọ́sọ́nà òye àtinúwá. Nípa èyí ni a ṣe ń ṣàmúlò àwọn ohun àmúṣọrọ̀ fún ìgbáyé-gbádùn.