የቅዱስ ቁርዓን ይዘት ትርጉም - የዮሩባ ትርጉም - አቡ ረሒማ ሚካኢል

Al-Buruuj

external-link copy
1 : 85

وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلۡبُرُوجِ

(Allāhu) fi sánmọ̀ tí àwọn ibùsọ̀ (òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀) wà nínú rẹ̀ búra. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 85

وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡمَوۡعُودِ

Ó tún fi ọjọ́ tí wọ́n ṣe ní àdéhùn (ìyẹn Ọjọ́ Àjíǹde) búra. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 85

وَشَاهِدٖ وَمَشۡهُودٖ

Ó tún fi olùjẹ́rìí àti ohun tó jẹ́rìí sí búra. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 85

قُتِلَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡأُخۡدُودِ

A ṣẹ́bi lé àwọn tó gbẹ́ kòtò (iná), info
التفاسير:

external-link copy
5 : 85

ٱلنَّارِ ذَاتِ ٱلۡوَقُودِ

(ìyẹn) iná tí wọ́n ń fi igi kò (nínú kòtò). info
التفاسير:

external-link copy
6 : 85

إِذۡ هُمۡ عَلَيۡهَا قُعُودٞ

(Rántí) nígbà tí wọ́n jókòó sí ìtòsí rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 85

وَهُمۡ عَلَىٰ مَا يَفۡعَلُونَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ شُهُودٞ

Wọ́n sì ń wo ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 85

وَمَا نَقَمُواْ مِنۡهُمۡ إِلَّآ أَن يُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَمِيدِ

Wọn kò rí àlèébù kan (wọn kò sì kórira kiní kan) lára wọn bí kò ṣe pé, wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, Alágbára, Ẹlẹ́yìn, info
التفاسير:

external-link copy
9 : 85

ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ شَهِيدٌ

Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ni Ẹlẹ́rìí lórí gbogbo n̄ǹkan. info
التفاسير:

external-link copy
10 : 85

إِنَّ ٱلَّذِينَ فَتَنُواْ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ ثُمَّ لَمۡ يَتُوبُواْ فَلَهُمۡ عَذَابُ جَهَنَّمَ وَلَهُمۡ عَذَابُ ٱلۡحَرِيقِ

Dájúdájú àwọn tó fi ìnira kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, lẹ́yìn náà tí wọn kò ronú pìwàdà, ìyà iná Jahanamọ ń bẹ fún wọn. Ìyà iná tó ń jó sì wà fún wọn. info
التفاسير:

external-link copy
11 : 85

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّٰلِحَٰتِ لَهُمۡ جَنَّٰتٞ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡكَبِيرُ

Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tiwọn ni àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ ńlá. info
التفاسير:

external-link copy
12 : 85

إِنَّ بَطۡشَ رَبِّكَ لَشَدِيدٌ

Dájúdájú ìgbámú ti Olúwa rẹ mà le. info
التفاسير:

external-link copy
13 : 85

إِنَّهُۥ هُوَ يُبۡدِئُ وَيُعِيدُ

Dájúdájú Òun ni Ó pìlẹ̀ (ẹ̀dá), Ó sì máa dá (ẹ̀dá) padà (fún àjíǹde). info
التفاسير:

external-link copy
14 : 85

وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلۡوَدُودُ

Òun ni Aláforíjìn, Olólùfẹ́ (ẹ̀dá), info
التفاسير:

external-link copy
15 : 85

ذُو ٱلۡعَرۡشِ ٱلۡمَجِيدُ

Òun l’Ó ni Ìtẹ́-ọlá, Ológo (Ẹni-ọ̀wọ̀ jùlọ), info
التفاسير:

external-link copy
16 : 85

فَعَّالٞ لِّمَا يُرِيدُ

Olùṣe-ohun-t’Ó-bá-fẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
17 : 85

هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ ٱلۡجُنُودِ

Ṣebí ìró àwọn ọmọ ogun ti dé ọ̀dọ̀ rẹ, info
التفاسير:

external-link copy
18 : 85

فِرۡعَوۡنَ وَثَمُودَ

(ọmọ ogun) Fir‘aon àti (ìjọ) Thamūd? info
التفاسير:

external-link copy
19 : 85

بَلِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي تَكۡذِيبٖ

Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì ń pe òdodo ní irọ́. info
التفاسير:

external-link copy
20 : 85

وَٱللَّهُ مِن وَرَآئِهِم مُّحِيطُۢ

Allāhu sì yí wọn ká lẹ́yìn wọn. info
التفاسير:

external-link copy
21 : 85

بَلۡ هُوَ قُرۡءَانٞ مَّجِيدٞ

Àmọ́ sá, ohun (tí A fi ránṣẹ́ sí ọ ni) al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé, info
التفاسير:

external-link copy
22 : 85

فِي لَوۡحٖ مَّحۡفُوظِۭ

tí ó wà nínú wàláà tí wọ́n ń ṣọ́. info
التفاسير: