Қуръони Карим маъноларининг таржимаси - Йўрубача таржима - Абу Раҳима Микоил

Бет рақами:close

external-link copy
65 : 19

رَّبُّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا فَٱعۡبُدۡهُ وَٱصۡطَبِرۡ لِعِبَٰدَتِهِۦۚ هَلۡ تَعۡلَمُ لَهُۥ سَمِيّٗا

Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀? info
التفاسير:

external-link copy
66 : 19

وَيَقُولُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَءِذَا مَا مِتُّ لَسَوۡفَ أُخۡرَجُ حَيًّا

Ènìyàn ń wí pé: “Ṣé nígbà tí mo bá kú, wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?” info
التفاسير:

external-link copy
67 : 19

أَوَلَا يَذۡكُرُ ٱلۡإِنسَٰنُ أَنَّا خَلَقۡنَٰهُ مِن قَبۡلُ وَلَمۡ يَكُ شَيۡـٔٗا

Ṣé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan? info
التفاسير:

external-link copy
68 : 19

فَوَرَبِّكَ لَنَحۡشُرَنَّهُمۡ وَٱلشَّيَٰطِينَ ثُمَّ لَنُحۡضِرَنَّهُمۡ حَوۡلَ جَهَنَّمَ جِثِيّٗا

Nítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn aṣ-ṣaetọ̄n jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
69 : 19

ثُمَّ لَنَنزِعَنَّ مِن كُلِّ شِيعَةٍ أَيُّهُمۡ أَشَدُّ عَلَى ٱلرَّحۡمَٰنِ عِتِيّٗا

Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan ẹni tí ó le jùlọ nínú wọn níbi ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé. info
التفاسير:

external-link copy
70 : 19

ثُمَّ لَنَحۡنُ أَعۡلَمُ بِٱلَّذِينَ هُمۡ أَوۡلَىٰ بِهَا صِلِيّٗا

Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí wíwọ inú Iná. info
التفاسير:

external-link copy
71 : 19

وَإِن مِّنكُمۡ إِلَّا وَارِدُهَاۚ كَانَ عَلَىٰ رَبِّكَ حَتۡمٗا مَّقۡضِيّٗا

Kò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀ (àfi kí ó gba ibẹ̀ kọjá). Ó di dandan kí ó ṣẹlẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa rẹ. info
التفاسير:

external-link copy
72 : 19

ثُمَّ نُنَجِّي ٱلَّذِينَ ٱتَّقَواْ وَّنَذَرُ ٱلظَّٰلِمِينَ فِيهَا جِثِيّٗا

Lẹ́yìn náà, A máa gba àwọn tó bẹ̀rù (Allāhu) là. A sì máa fi àwọn alábósì sílẹ̀ sínú Iná lórí ìkúnlẹ̀.[1] info

1. Ìgbàkígbà tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” bíi “A” tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò afarajorúkọ bíi “Àwa” fún Ara Rẹ̀, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ àpọ́nlé fún Un, kì í ṣe pé Ẹni tó ń jẹ́ “Allāhu” pé méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

التفاسير:

external-link copy
73 : 19

وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتُنَا بَيِّنَٰتٖ قَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لِلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَيُّ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ خَيۡرٞ مَّقَامٗا وَأَحۡسَنُ نَدِيّٗا

Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) ló lóore jùlọ ní ibùgbé, ló sì dára jùlọ ní ìjókòó (afẹ́)?” info
التفاسير:

external-link copy
74 : 19

وَكَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّن قَرۡنٍ هُمۡ أَحۡسَنُ أَثَٰثٗا وَرِءۡيٗا

Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jù wọ́n lọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí! info
التفاسير:

external-link copy
75 : 19

قُلۡ مَن كَانَ فِي ٱلضَّلَٰلَةِ فَلۡيَمۡدُدۡ لَهُ ٱلرَّحۡمَٰنُ مَدًّاۚ حَتَّىٰٓ إِذَا رَأَوۡاْ مَا يُوعَدُونَ إِمَّا ٱلۡعَذَابَ وَإِمَّا ٱلسَّاعَةَ فَسَيَعۡلَمُونَ مَنۡ هُوَ شَرّٞ مَّكَانٗا وَأَضۡعَفُ جُندٗا

Sọ pé: “Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun. info
التفاسير:

external-link copy
76 : 19

وَيَزِيدُ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ٱهۡتَدَوۡاْ هُدٗىۗ وَٱلۡبَٰقِيَٰتُ ٱلصَّٰلِحَٰتُ خَيۡرٌ عِندَ رَبِّكَ ثَوَابٗا وَخَيۡرٞ مَّرَدًّا

Allāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn tó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ. info
التفاسير: