قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ - ابو رحیمہ مائیکل

صفحہ نمبر:close

external-link copy
48 : 74

فَمَا تَنفَعُهُمۡ شَفَٰعَةُ ٱلشَّٰفِعِينَ

Ìpẹ̀ àwọn olùṣìpẹ̀ kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. info
التفاسير:

external-link copy
49 : 74

فَمَا لَهُمۡ عَنِ ٱلتَّذۡكِرَةِ مُعۡرِضِينَ

Kí ló mú wọn ná tí wọ́n ń gbúnrí kúrò níbi ìrántí info
التفاسير:

external-link copy
50 : 74

كَأَنَّهُمۡ حُمُرٞ مُّسۡتَنفِرَةٞ

bí ẹni pé àwọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó ń sá lọ, info
التفاسير:

external-link copy
51 : 74

فَرَّتۡ مِن قَسۡوَرَةِۭ

tó sá fún kìnìhún? info
التفاسير:

external-link copy
52 : 74

بَلۡ يُرِيدُ كُلُّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ أَن يُؤۡتَىٰ صُحُفٗا مُّنَشَّرَةٗ

Rárá, ńṣe ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń fẹ́ kí Á fún òun náà ní Tírà tí ó máa ṣeé tẹ́ han àwọn ènìyàn (bíi ti al-Ƙur’ān). info
التفاسير:

external-link copy
53 : 74

كَلَّاۖ بَل لَّا يَخَافُونَ ٱلۡأٓخِرَةَ

Rárá. Wọn kò páyà ọ̀run ni. info
التفاسير:

external-link copy
54 : 74

كَلَّآ إِنَّهُۥ تَذۡكِرَةٞ

Ẹ gbọ́! Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ìrántí. info
التفاسير:

external-link copy
55 : 74

فَمَن شَآءَ ذَكَرَهُۥ

Nítorí náà, ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó rántí rẹ̀. info
التفاسير:

external-link copy
56 : 74

وَمَا يَذۡكُرُونَ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ هُوَ أَهۡلُ ٱلتَّقۡوَىٰ وَأَهۡلُ ٱلۡمَغۡفِرَةِ

Wọn kò sì níí rántí (al-Ƙur’ān) àfi tí Allāhu bá fẹ́. (Allāhu) Òun l’a gbọ́dọ̀ bẹ̀rù. Òun l’ó sì ni àforíjìn. info
التفاسير: