قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ - ابو رحیمہ مائیکل

Al-Mum'tahanah

external-link copy
1 : 60

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ عَدُوِّي وَعَدُوَّكُمۡ أَوۡلِيَآءَ تُلۡقُونَ إِلَيۡهِم بِٱلۡمَوَدَّةِ وَقَدۡ كَفَرُواْ بِمَا جَآءَكُم مِّنَ ٱلۡحَقِّ يُخۡرِجُونَ ٱلرَّسُولَ وَإِيَّاكُمۡ أَن تُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ رَبِّكُمۡ إِن كُنتُمۡ خَرَجۡتُمۡ جِهَٰدٗا فِي سَبِيلِي وَٱبۡتِغَآءَ مَرۡضَاتِيۚ تُسِرُّونَ إِلَيۡهِم بِٱلۡمَوَدَّةِ وَأَنَا۠ أَعۡلَمُ بِمَآ أَخۡفَيۡتُمۡ وَمَآ أَعۡلَنتُمۡۚ وَمَن يَفۡعَلۡهُ مِنكُمۡ فَقَدۡ ضَلَّ سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀tá Mi àti ọ̀tá yín ní ọ̀rẹ́ tí ẹ óò máa fi ìfẹ́ hàn sí. Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ó dé ba yín nínú òdodo. Wọ́n yọ Òjíṣẹ́ àti ẹ̀yin náà kúrò nínú ìlú nítorí pé, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu, Olúwa yín. Tí ẹ̀yin bá jáde fún ogun ní ojú-ọ̀nà Mi àti nítorí wíwá ìyọ́nú Mi, (ṣé) ẹ̀yin yóò tún máa ní ìfẹ́ kọ̀rọ̀ sí wọn ni! Èmi sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ fi pamọ́ àti ohun tí ẹ fi hàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yín, dájúdájú ó ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà. info
التفاسير:

external-link copy
2 : 60

إِن يَثۡقَفُوكُمۡ يَكُونُواْ لَكُمۡ أَعۡدَآءٗ وَيَبۡسُطُوٓاْ إِلَيۡكُمۡ أَيۡدِيَهُمۡ وَأَلۡسِنَتَهُم بِٱلسُّوٓءِ وَوَدُّواْ لَوۡ تَكۡفُرُونَ

Tí ọwọ́ wọn bá bà yín, wọ́n máa di ọ̀tá fún yín. Wọn yó sì fi ọwọ́ wọn àti ahọ́n wọn nawọ́ aburú si yín. Wọ́n sì máa fẹ́ kí ó jẹ́ pé ẹ di aláìgbàgbọ́. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 60

لَن تَنفَعَكُمۡ أَرۡحَامُكُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُكُمۡۚ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَفۡصِلُ بَيۡنَكُمۡۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ

Àwọn ẹbí yín àti àwọn ọmọ yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní; ní Ọjọ́ Àjíǹde ni Allāhu máa ṣèpínyà láààrin yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 60

قَدۡ كَانَتۡ لَكُمۡ أُسۡوَةٌ حَسَنَةٞ فِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥٓ إِذۡ قَالُواْ لِقَوۡمِهِمۡ إِنَّا بُرَءَٰٓؤُاْ مِنكُمۡ وَمِمَّا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ كَفَرۡنَا بِكُمۡ وَبَدَا بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمُ ٱلۡعَدَٰوَةُ وَٱلۡبَغۡضَآءُ أَبَدًا حَتَّىٰ تُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ وَحۡدَهُۥٓ إِلَّا قَوۡلَ إِبۡرَٰهِيمَ لِأَبِيهِ لَأَسۡتَغۡفِرَنَّ لَكَ وَمَآ أَمۡلِكُ لَكَ مِنَ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖۖ رَّبَّنَا عَلَيۡكَ تَوَكَّلۡنَا وَإِلَيۡكَ أَنَبۡنَا وَإِلَيۡكَ ٱلۡمَصِيرُ

Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fún yín ní ara (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún ìjọ wọn pé: "Dájúdájú àwa yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. A takò yín. Ọ̀tá àti ìkórira sì ti hàn láààrin wa títí láéláé àyàfi ìgbà tí ẹ bá tó gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. - Àfi ọ̀rọ̀ tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Dájúdájú mo máa tọrọ àforíjìn fún ọ, èmi kò sì ní ìkápá kiní kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu. - Olúwa wa, Ìwọ l’a gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ l’a ṣẹ́rí padà sí (nípa ìronúpìwàdà). Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 60

رَبَّنَا لَا تَجۡعَلۡنَا فِتۡنَةٗ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ وَٱغۡفِرۡ لَنَا رَبَّنَآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ

Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́.[1] Foríjìn wá, Olúwa wa. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.” info

1. Ìyẹn ni pé, má fi àwọn kèfèrí borí wa, kí ayé má fi lérò pé wọ́n wà lórí òdodo ni wọ́n fi borí wa.

التفاسير: