قرآن کریم کے معانی کا ترجمہ - یوروبا ترجمہ - ابو رحیمہ مائیکل

صفحہ نمبر:close

external-link copy
59 : 40

إِنَّ ٱلسَّاعَةَ لَأٓتِيَةٞ لَّا رَيۡبَ فِيهَا وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يُؤۡمِنُونَ

Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀, kò sì sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ni kò gbàgbọ́. info
التفاسير:

external-link copy
60 : 40

وَقَالَ رَبُّكُمُ ٱدۡعُونِيٓ أَسۡتَجِبۡ لَكُمۡۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَسۡتَكۡبِرُونَ عَنۡ عِبَادَتِي سَيَدۡخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ

Olúwa yín sọ pé: “Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn tó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi,[1] wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ.” info

1. Ẹ wo sūrah Yūnus; 10:22 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ rẹ̀.

التفاسير:

external-link copy
61 : 40

ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِتَسۡكُنُواْ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبۡصِرًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ

Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe òru fún yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó sì ṣe) ọ̀sán (nítorí kí ẹ lè fi) ríran. Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kì í dúpẹ́ (fún Un). info
التفاسير:

external-link copy
62 : 40

ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٖ لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ

Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo? info
التفاسير:

external-link copy
63 : 40

كَذَٰلِكَ يُؤۡفَكُ ٱلَّذِينَ كَانُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ

Báyẹn náà ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́ àwọn tó ń tako àwọn āyah Allāhu lórí kúrò níbi òdodo (ṣíwájú tiwọn). info
التفاسير:

external-link copy
64 : 40

ٱللَّهُ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ قَرَارٗا وَٱلسَّمَآءَ بِنَآءٗ وَصَوَّرَكُمۡ فَأَحۡسَنَ صُوَرَكُمۡ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡۖ فَتَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Allāhu ni Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fún yín ní ibùgbé. Ó sì ṣe sánmọ̀ ní àjà (le yín lórí). Ó ya àwòrán yín. Ó sì ya àwòrán yín dáradára. Ó pèsè arísìkí fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, mímọ́ ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير:

external-link copy
65 : 40

هُوَ ٱلۡحَيُّ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ فَٱدۡعُوهُ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَۗ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Òun ni Alààyè. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Nítorí náà, ẹ pè É lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1] Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah Al-’a‘rọ̄f; 7:29.

التفاسير:

external-link copy
66 : 40

۞ قُلۡ إِنِّي نُهِيتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَمَّا جَآءَنِيَ ٱلۡبَيِّنَٰتُ مِن رَّبِّي وَأُمِرۡتُ أَنۡ أُسۡلِمَ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ

Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi pé kí n̄g jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, nígbà tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (kí n̄g jẹ́ mùsùlùmí) fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá. info
التفاسير: