Kur'an-ı Kerim meal tercümesi - Yorba Dilinde Tercüme - Ebu Rahime Mikail

external-link copy
74 : 7

وَٱذۡكُرُوٓاْ إِذۡ جَعَلَكُمۡ خُلَفَآءَ مِنۢ بَعۡدِ عَادٖ وَبَوَّأَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ تَتَّخِذُونَ مِن سُهُولِهَا قُصُورٗا وَتَنۡحِتُونَ ٱلۡجِبَالَ بُيُوتٗاۖ فَٱذۡكُرُوٓاْ ءَالَآءَ ٱللَّهِ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ

Ẹ tún rántí nígbà tí (Allāhu) ṣe yín ní àrólé lẹ́yìn àwọn ara ‘Ād. Ó sì fún yín ní ilé ìgbé lórí ilẹ̀; ẹ̀ ń kọ́ ilé ńláńlá sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹ sì ń gbẹ́ àwọn ilé sínú àpáta. Ẹ rántí àwọn ìdẹ̀ra Allāhu, kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀. info
التفاسير: