1. Ìyẹn ni pé, tí ẹ̀dá bá lérò pé, bí òun bá sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀, ó yẹ kí ẹ̀dá náà mọ̀ dájú pé, nínú ìròyìn Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ni pé, Ẹlẹ́dàá nímọ̀ èrò-ọkàn àwọn ẹ̀dá Rẹ̀, áḿbọ̀sìbọ́sí ọ̀rọ̀ tí àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ sọ ní ìkọ̀kọ̀. Ìtúmọ̀ kejí: “Ṣé Allāhu kò mọ ẹni tí Ó ṣẹ̀dá ni?” Ìyẹn ni pé, ṣé Allāhu kò mọ àwọn ẹ̀dá Rẹ̀ tòhun tí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn, ọ̀rọ̀ gban̄gba wọn àti èrò-ọkàn wọn? Allāhu mọ gbogbo rẹ̀.