ශුද්ධවූ අල් කුර්ආන් අර්ථ කථනය - යුරෝපීය පරිවර්තනය - අබූ රහීමා මයිකල්

Az-Zukh'ruf

external-link copy
1 : 43

حمٓ

Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)[1] info

1. Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al Baƙọrah; 2:1.

التفاسير:

external-link copy
2 : 43

وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ

(Allāhu) fi Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra. info
التفاسير:

external-link copy
3 : 43

إِنَّا جَعَلۡنَٰهُ قُرۡءَٰنًا عَرَبِيّٗا لَّعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ

Dájúdájú Àwa se é ní al-Ƙur’ān (n̄ǹkan kíké) ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè. info
التفاسير:

external-link copy
4 : 43

وَإِنَّهُۥ فِيٓ أُمِّ ٱلۡكِتَٰبِ لَدَيۡنَا لَعَلِيٌّ حَكِيمٌ

Àti pé dájúdájú nínú Tírà Ìpìlẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ Wa, al-Ƙur’ān mà ga, ó sì kún fún ọgbọ́n. info
التفاسير:

external-link copy
5 : 43

أَفَنَضۡرِبُ عَنكُمُ ٱلذِّكۡرَ صَفۡحًا أَن كُنتُمۡ قَوۡمٗا مُّسۡرِفِينَ

Ṣé kí Á ká Tírà Ìrántí (al-Ƙur’ān) kúrò nílẹ̀ fún yín pátápátá (kí Á máa wò yín ní ìran) nítorí pé, ẹ jẹ́ ìjọ alákọyọ? info
التفاسير:

external-link copy
6 : 43

وَكَمۡ أَرۡسَلۡنَا مِن نَّبِيّٖ فِي ٱلۡأَوَّلِينَ

Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí A ti rán sí àwọn ẹni àkọ́kọ́. info
التفاسير:

external-link copy
7 : 43

وَمَا يَأۡتِيهِم مِّن نَّبِيٍّ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ

Kò sí Ànábì kan tí ó wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́. info
التفاسير:

external-link copy
8 : 43

فَأَهۡلَكۡنَآ أَشَدَّ مِنۡهُم بَطۡشٗا وَمَضَىٰ مَثَلُ ٱلۡأَوَّلِينَ

Nítorí náà, A ti pa àwọn tó ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) rẹ́. Àpèjúwe (ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì ti ṣíwájú. info
التفاسير:

external-link copy
9 : 43

وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ لَيَقُولُنَّ خَلَقَهُنَّ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡعَلِيمُ

Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Ẹni tó dá wọn ni Alágbára, Onímọ̀; info
التفاسير:

external-link copy
10 : 43

ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ مَهۡدٗا وَجَعَلَ لَكُمۡ فِيهَا سُبُلٗا لَّعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ

Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ fún yín. Ó sì fi àwọn ojú ọ̀nà sínú rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà; info
التفاسير: