1. Kíyè sí i! Ìtàn kan gbajúmọ̀ nínú àwọn tírà Tafsīr pé, àwọn mẹ́ta kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Ànábì ‘Īsā ọmọ Mọryam - kí ọlà Allāhu máa bá a - tí ó rán níṣẹ́ lọ sí ìlú Antiok ni àwọn Òjíṣẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà. Àmọ́ nínú Tafsīr Ibn Kathīr, ó sọ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nítorí náà, má ṣe gbaralé ìtàn náà. Èyí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ni pé, wọ́n jẹ́ ara àwọn Òjíṣẹ́ tí Allāhu kò dárúkọ wọn fún Ànábì wa Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.