Tradução dos significados do Nobre Qur’an. - Tradução européia - Abu Rahima Mikhail

external-link copy
103 : 9

خُذۡ مِنۡ أَمۡوَٰلِهِمۡ صَدَقَةٗ تُطَهِّرُهُمۡ وَتُزَكِّيهِم بِهَا وَصَلِّ عَلَيۡهِمۡۖ إِنَّ صَلَوٰتَكَ سَكَنٞ لَّهُمۡۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ

Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.[1] info

1. Àwọn ikọ̀ méjì ni āyah yìí ń sọ nípa wọn. Ikọ̀ kìíní ni àwọn tó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá wọn - ní ìbámu sí āyah 102 tó ṣíwájú. Ikọ̀ kejì ni àwọn tó ń yọ zakāh. Zakāh yíyọ sì jẹ́ àfọ̀mọ́ dúkìá fún ẹni tí ó yọ ọ́.

التفاسير: