Tradução dos significados do Nobre Qur’an. - Tradução européia - Abu Rahima Mikhail

Número de página:close

external-link copy
64 : 29

وَمَا هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَآ إِلَّا لَهۡوٞ وَلَعِبٞۚ وَإِنَّ ٱلدَّارَ ٱلۡأٓخِرَةَ لَهِيَ ٱلۡحَيَوَانُۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ

Kí ni ìṣẹ̀mí ayé yìí bí kò ṣe ìranù àti eré ṣíṣe. Àti pé dájúdájú Ilé Ìkẹ́yìn sì ni ìṣẹ̀mí gbére tí wọ́n bá mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
65 : 29

فَإِذَا رَكِبُواْ فِي ٱلۡفُلۡكِ دَعَوُاْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ فَلَمَّا نَجَّىٰهُمۡ إِلَى ٱلۡبَرِّ إِذَا هُمۡ يُشۡرِكُونَ

Nígbà tí wọ́n bá gun ọkọ̀ ojú-omi, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un.[1] Àmọ́ nígbà tí Ó bá gbà wọ́n là sí orí ilẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa ṣẹbọ info

1. Ẹ wo sūrah Yūnus; 10:22 àti ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ rẹ̀.

التفاسير:

external-link copy
66 : 29

لِيَكۡفُرُواْ بِمَآ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ وَلِيَتَمَتَّعُواْۚ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ

nítorí kí wọ́n lè ṣàì moore sí n̄ǹkan tí A fún wọn àti nítorí kí wọ́n lè jayékáyé. Nítorí náà, láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀. info
التفاسير:

external-link copy
67 : 29

أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا جَعَلۡنَا حَرَمًا ءَامِنٗا وَيُتَخَطَّفُ ٱلنَّاسُ مِنۡ حَوۡلِهِمۡۚ أَفَبِٱلۡبَٰطِلِ يُؤۡمِنُونَ وَبِنِعۡمَةِ ٱللَّهِ يَكۡفُرُونَ

Ṣé wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa ṣe Haram (Mọkkah) ni àyè ìfàyàbalẹ̀, tí wọ́n sì ń jí àwọn ènìyàn gbé lọ ní àyíká wọn? Ṣé irọ́ (òrìṣà) ni wọn yóò gbàgbọ́, tí wọn yó sì ṣàì moore sí ìdẹ̀ra Allāhu? info
التفاسير:

external-link copy
68 : 29

وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوۡ كَذَّبَ بِٱلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُۥٓۚ أَلَيۡسَ فِي جَهَنَّمَ مَثۡوٗى لِّلۡكَٰفِرِينَ

Ta ló ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, tàbí tó pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá a? Ṣé inú iná Jahanamọ kọ́ ni ibùgbé fún àwọn aláìgbàgbọ́ ni? info
التفاسير:

external-link copy
69 : 29

وَٱلَّذِينَ جَٰهَدُواْ فِينَا لَنَهۡدِيَنَّهُمۡ سُبُلَنَاۚ وَإِنَّ ٱللَّهَ لَمَعَ ٱلۡمُحۡسِنِينَ

Àwọn tó gbìyànjú nípa Wa, dájúdájú A máa fi wọ́n mọ àwọn ọ̀nà Wa. Àti pé dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú àwọn olúṣe-rere. info
التفاسير: