1. Kíyè sí i, àwọn āyah yìí (99 àti 100) ti fi rinlẹ̀ pé kò sí ìpadàsáyé fún àwọn òkú.
1. Ìyẹn ní kété tí olúkùlùkù bá kọ́kọ́ jí dìde láti inú sàréè rẹ̀. Iyè yóò pamọ́ àwọn ẹ̀dá nínú lásìkò náà ni, àmọ́ nígbà tí àwọn mọlāika bá da àwọn ẹ̀dá lọ sí ọ̀dọ̀ Allāhu Ọba Olùdájọ́ àwọn ẹ̀dá máa bẹ̀rẹ̀ sí i bira wọn léèrè ìbéèrè ní ti àbámọ̀ àti ìtakora.